Lẹyin  ti wọn ji owo tan, awọn adigunjale pa ọdẹ to n sọ ileepo kan n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ko si bi eeyan yoo ṣe ri oku baba eni ọdun mẹtalelogoji (43) kan, Isau Yisah, to na gbalaja sinu ileepo kan laduugbo Mọniya, n’Ibadan, ti ara oluwa ẹ ko  ni i wa riri fun ibẹru tabi aanu ikunlẹ abiamọ pẹlu bi wọn ṣe yinbọn pa a, ti oku rẹ si wa ninu agbara ẹjẹ nibi ti wọn pa a si.

Isah, ọdẹ to n ṣọ ileepo kan ti wọn n pe ni Tybato Filling Station, lagbegbe Mọniya n’Ibadan, yii ni wọn pa a si ẹgbẹ kan ninu ọgba ileepo naa loru mọju ọjọ Abamẹta .

Awọn adugunjale la gbọ pe wọn pa a ki wọn tọọ deede ba oku ẹ ninu agbara ẹjẹ nilẹẹlẹ nibẹ.

Bo tilẹ jẹ pe iṣẹlẹ ọhun ko  ṣoju ẹnikẹni, awọn to n gbe tosi ileepo naa fidi ẹ mulẹ pe awọn adugunjale kan ya wọ agbegbe naa loru mọju aarọ yii (ọjọ Abamẹta, Satide), o si ṣee ṣe ko jẹ pe awọn ni wọn pa baba ọdẹ naa nigba to gbiyanju lati da wọn lọwọ kọ.

 

Wọn ni akitiyan ọkunrin ọdẹ yii ko seso rere nitori awọn ole naa papa pitu ọwọ wọn pẹlu bi wọn ṣe ja ilẹkun ọfiisi ẹni to ni ileepo naa, ti wọn si ji tẹlifiṣan ati owo ti ẹnikẹni ko tí ì mọ iye ẹ gbe lọ.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yìí mulẹ, Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, SP Olugbenga Fadeyi, sọ pe oju ọgbẹ nla kan wa lori Oloogbe Isah, eyi to fi han pe apola igi ni wọn fi pa a nitori ẹjẹ wa loju ọgbẹ naa, eyi to ṣan kaakiri ara ẹ, wọn si ba apola igi ọhun nitosi ibi ti wọn ti ba oku ẹ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Awọn ọlọpaa ti gbe oku naa lọ si mọṣuari, iwadii si ti bẹrẹ lati ṣawari awọn ọdaran to pa ọkunrin yẹn.

” Ọga agba awọn ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ, CP Joe Nwachukwu Enwonwu, fi asiko yii rọ awọn ara agbegbe yẹn lati fọwọ sowọ pọ pẹlu awọn agbofinro ninu ilakaka wọn lati ri awọn ọdaran yẹn mu.”

Leave a Reply