Jọkẹ Amọri
Ọkan ninu awọn adẹrin-in poṣonu ilẹ wa, Abdulgafar Ahmed Abiọla, ti gbogbo eeyan mọ si Cute Abiọla, ti Gomina ipinlẹ Kwara, Abdul Rahman AbdulRazaq, ṣẹṣẹ fi ṣe oludamọran pataki rẹ lori ọrọ to ba jẹ mọ iṣẹ ọna, iyẹn Special Assistant on Creative Industries, ti kọwe fiṣẹ silẹ nibi iṣẹ ọmọ ogun oju omi, Nigerian Navy to ti n ṣiṣẹ. O loun ti fẹyinti bayii, oun ko ṣiṣẹ naa mọ.
Ninu lẹta kan to kọ si awọn ọga rẹ ni ileesẹ ologun ọhun, eyi to gbe sori Instagraamu rẹ lo ti kọ ọ bayii pe ‘‘Pẹlu ẹmi imoore ni mo ṣe fi tọkantọkan dupẹ lọwọ ileeṣẹ ọmọ ogun oju omi ilẹ wa, Nigerian Navy, fun anfaani ti ko wọpọ ti wọn fun mi lati ni ikoraro ati ikora ẹni ni ijanu, eyi ti wọn fi se mi jinna daadaa lori iṣẹ ti mo yan laayo, ẹkọ iwa ọmọluabi, awọn iwa ti iṣẹ naa pe fun, ati bẹẹ bẹẹ lọ. Mo le fi gbogbo ẹnu sọ ọ pe mo ni ẹkọ to yẹ ni gbogbo ọna lati le tẹsiwaju lati maa gbe igbe aye to daa, to si wuyi lọjọ iwaju.
‘‘Mo rọ gbogbo ẹyin ololufẹ mi pe kẹ ẹ ba mi dupẹ lọwọ ọga agba patapata fun awọn ọmọ ogun oju omi ilẹ wa, ati gbogbo awọn aṣiwaju mi lẹnu iṣẹ yii ti wọn ko ipa kan tabi omi ninu idagbasoke mi lori iṣẹ ti mo yan laayo yii, paapaa ju lọ bi mo ṣe bu mu ninu omi ọgbọn tiwọn naa lati mu ki erongba mi lati daabo bo, ati lati gbeja orileede mi ṣee ṣe. Anfaani ẹyọ kan yii lati ọdọ ọga ologun yii jọ mi loju, o si fi han bi ileeṣẹ ologun ṣe ni ifẹ lati mu ki erongba awọn oṣiṣẹ wọn ṣee ṣe.
‘‘Mo ṣi jẹ ọkan ninu awọn mọlẹbi ileeṣẹ ọmọ ogun oju omi, mo si ṣeleri pe n oo maa jẹ aṣoju rere fun ileeṣẹ ologun oju omi ni orileede yii tabi ni oke okun. O jẹ ohun iwuri fun mi lati ṣiṣẹ ni iru ileeṣẹ bii ti ologun oju omi ilẹ wa yii.
‘‘Mo fẹẹ fi tọkantọkan mọ riri gbogbo awọn aṣiwaju mi nidii iṣẹ yii ti wọn jẹ ohun eelo fun aṣeyọri mi. Adura mi ni pe atẹgun ati omi ko ni i kọju ija si yin bi ẹ ṣe n rin lori omi, nitori mo mọ pe titi lae lẹ oo maa jẹ olootitọ.
‘‘Mo dupẹ lọwọ yin o, ileesẹ ologun oju omi ilẹ wa.
Gbogbo wa la o jọ tẹsiwaju’’.
Bi Abdulgafar ti awọn ololufẹ rẹ maa n pe ni Cute Abiọla ṣe kọ ọrọ naa sori ikanni Instagraamu rẹ ree, to fi dupẹ lọwọ awọn ọga rẹ.
Bẹẹ lawọn ololufẹ rẹ naa ti n ki i ku oriire, ti wọn ṣi n gbadura fun un pe igbesẹ tuntun to ṣẹṣẹ gbe yii yoo san an si rere, ohun to daa ni yoo mu bọ nibẹ.