Monisọla Saka
Bi gbogbo nnkan ba lọ bi oṣere-binrin ilẹ wa nni, Mercy Aigbe, to ti yi orukọ rẹ pada si Minnah bayii ṣe pinnu rẹ, ko ni i pẹ rara, ti oṣere ilẹ wa naa yoo fi wẹ wonka, ti yoo si lọ si Mecca, toun naa yoo fi eyin sẹnu, ti yoo di Alaaja.
Eyi ko sẹyin bi oṣere naa ṣe kede ni gbangba bayii pe oun ko ṣe ẹsin Kirisitẹni mọ, Musulumi ododo loun bayii, ki ọdun ta a wa ninu rẹ yii si too pari, oun maa lọ si Mecca. Latigba ti Mercy ti fẹ ọkọ rẹ, Kazim Adeoti, toun jẹ Musulumi lo ti n sọ pe oun ti gba ẹsin Anọbi.
Bo tilẹ jẹ pe ọpọ ni ko gba oṣere naa gbọ, iṣẹlẹ to ṣẹlẹ laipẹ yii, iyẹn waasi aawẹ Ramadan ti oun ati ọkọ rẹ ṣagbatẹru rẹ to waye ti fi han pe ootọ ni ọmobinrin naa n sọ, nitori lẹyin eto naa to ba awọn oniroyin sọrọ lo sọ pe oun ti di Musulumi bayii, laipẹ rara loun yoo si lọ si Mecca lati ṣiṣẹ laada.
Obinrin toun pẹlu ọkọ ẹ, Kazim Adeoti, to jẹ gbajugbaja alagbata sinima agbelewo Yoruba, tawọn eeyan mọ si Adekaz, jọ ṣegbeyawo bonkẹlẹ ninu oṣu Kejila, ọdun 2021, sọ nibi waasi inu oṣu Ramadan ati apejẹ iṣinu aawẹ ọhun, eyi ti wọn pe awọn onitiata atawọn eeyan mi-in lati waa fijoko yẹ wọn si yii, ki wọn si bawọn jẹun pe, “Lagbara Ọlọrun, orukọ mi tuntun bayii ni Hajia Minnah Mercy Adeoti, Minnah ti ‘H’ pari ẹ ni kikọ silẹ ni o. Aliamudulilai. Inu mi dun gidigidi, ọkan mi si balẹ bii pe mo ti ni gbogbo nnkan ti mo n fẹ. Waasi inu Ramadan akọkọ ti mo maa kopa ninu ẹ niyi, bẹẹ ni mo mọ pe ọkan ninu opo ẹsin Islam ni aawẹ Ramadan jẹ, ka ko eeyan jọ, lati jẹ ki wọn mọ ohun ti Ọlọrun sọ ni, ka le baa tẹle ofin ti Ọlọrun ti la kalẹ fun wa, ati bi Anabi ṣe sọ ọ. Bakan naa lo jẹ akoko ayọ ati idunnu, tawọn eeyan maa jẹ, ti wọn maa mu, ti wọn tun maa dunnu sira wọn. Inu mi waa dun pe gbogbo awọn ta a pe ni wọn yẹ wa si”.
Bakan naa ni obinrin yii tun n fi gbogbo eleyii han ninu awọn imura ẹ lọlọkan-o-jọkan, agaga ninu awọn fọto to n gbe sori Instagraamu rẹ.
Fọto to kọkọ gbe sori Instagraamu lẹyin ti wọn ṣeto adura naa tan, nibi to ti wọ aṣọ gbagẹrẹ funfun pẹlu iborun funfun kan bayii, lo kọ ọ si bayii pe, “Imura mi fun eto waasi oṣu Ramadan temi pẹlu ọkọ mi, Kazim Adeoti, ṣe lanaa niyi. Ki Ọlọrun Allah fun wa lore-ọfẹ lati tun ṣe pupọ ẹ si i”.
Nigba ti wọn n beere pe bawo lo ṣe n ri awọn nnkan tuntun tuntun ninu ẹsin Musulumi yii kọ, lasiko ifọwọwerọ ti wọn ṣe fun un lẹyin eto ọhun, Mercy ṣalaye orukọ ẹ tuntun ati awọn nnkan to ti ri kọ lẹyin to di Musulumi, o ni, “Mo ti kọ bi wọn ṣe n kirun, mo ṣi n kọ ọ lọ naa ni o, mo dẹ mọ pe laipẹ, ma a tun mọ ọn si i. Mo dẹ tun n lọ silẹ mimọ Mẹka lọdun yii lagbara Ọlọrun. Mo tun lawọn oriṣiiriṣii eeyan ti wọn n ran mi lọwọ lori bi mo ṣe maa mọ awọn nnkan kan ninu Islaamu, ọkan ninu wọn ni ọrẹ mi, Kẹmi Afọlabi, o n ran mi lọwọ gidigidi ni, koda o tun ra aṣọ jalamia fun mi, bẹẹ lo n kọ mi lawọn oriṣiiriṣii nnkan to yẹ ki n mọ”.
Nigba to n ṣalaye itumọ orukọ ẹ, o ni,” Iyalẹnu ni bawọn eeyan ṣe n sọ pe iru orukọ wo ni mo n jẹ yii jẹ fun mi. Itumọ orukọ mi tuntun yii ni, ikẹ, ẹbun, aanu ati oore-ofẹ lati ọdọ Ọlọrun. Ọkọ mi lo dabaa ẹ fun mi, mo si fẹran orukọ yẹn lemi naa ṣe gba a lọwọ kan. Gbogbo awọn nnkan to jẹ mọ ẹsin Islam ti mo n sọ yii, mo kan n gbiyanju naa ni, nitori ọkọ mi lo n kọ mi, emi naa si ti n kirun, lagbara lọwọ Ọlọrun, emi naa yoo di Alaaja laipẹ, nitori mo n lọ si Mẹka lọdun yii, lati lọọ jọsin fun Ọlọrun gẹgẹ bi ọkan ninu opo ẹsin Islam”.
Oriṣiriṣii ni nnkan tawọn eeyan ori ẹrọ ayelujara ri sọ si igbesẹ tuntun ti Mercy gbe yii, nigba tawọn kan n bu u pe o gba ọkọ ọlọkọ, awọn mi-in ni o ṣi maa tun lọkọ tuntun mi-in. Ero awọn kan tilẹ yatọ gedegede lori ọrọ yii, wọn ni ki wọn fi obinrin naa silẹ, nitori bo ba ṣe wu alaye lo n ṣe aye ẹ.
Nnenna ni oun o ti i ri ọkunrin naa to maa mu koun fi ẹsin Kirisitẹni silẹ. Amọ ugezujugezu ni tiẹ fesi pe ki wọn fi i silẹ, o loun to wu u niyẹn, ko si yẹ kiyẹn jẹ inira fẹnikẹni.
Adeṣọla naa kin ẹni yii lẹyin, o loun lo ni aye ẹ, ko kan ẹnikẹni ninu awọn.
Ẹnikẹni to ba ri arẹwa oṣere tiata ilẹ wa naa bayii, Hajia Minnah ni ko pe e o, nitori oṣere naa ti n mura Mecca bayii.