Lẹyin wakati mẹrin to sọ funyawo rẹ pe aye ṣu oun, Fisayọ pokunso n’Ifẹ

Florence Babaṣọla

Titi di asiko ti a n koroyin yii jọ, ko si ẹni to le sọ ni pato, nnkan ti ọmọkunrin kan, Fisayọ Adeniyi, ri to fi deede sọ pe ile aye ṣu oun, to si pokunso.

Ẹka eto aabo ni ọgba Fasiti OAU ni Fisayọ ti n ṣiṣẹ, gbogbo awọn ojulumọ rẹ ni wọn si ṣapejuwe rẹ gẹgẹ bii ẹni to turaka si gbogbo eeyan, bẹẹ lawọn ti wọn jọ n gbe adugbo sọ pe ko sẹni to le fura iru igbesẹ bẹẹ si i rara.

Gbogbo awọn mọlẹbi Fisayọ ni wọn sọ pe ko si nnkan kan tawọn mọ pe o n ṣe e to fi le ro o pe iku lo yẹ ko kan, bẹẹ ni ko si kọ iwe silẹ rara lati sọ idi to fi ro gbogbo rẹ pin.

Ohun kan ṣoṣo ti a gbọ ni pe lọsan-an ọjọ Satide to kọja lo tẹ atẹjiṣẹ ori foonu si iya ati iyawo rẹ, o si sọ fun wọn pe aye ti su oun patapata. Bo ṣe kuro nibi iṣẹ niyẹn, to fori le ile rẹ to wa loju-ọna Ifẹwara, niluu Ileefẹ.

Bo ṣe dele lo ti gbogbo ilẹkun, to si pokunso sibẹ. Awọn ti wọn ri i nigba to wọle, ṣugbọn ti ko tete jade ni wọn lọ sẹnu ọna rẹ lati mọ nnkan to ṣẹlẹ si i, ṣugbọn iyalẹnu lo jẹ fun wọn lati ri i pe o ti pokunso.

Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa l’Ọṣun, SP Yẹmisi Ọpalọla, sọ pe wọn ko ti i fi ọrọ naa to oun leti, ṣugbọn Alukoro Fasiti OAU, Abiọdun Ọlanrewaju, sọ pe loootọ niṣẹlẹ naa.

Ọlanrewaju ṣalaye pe awọn alaṣẹ ba gbogbo mọlẹbi Fisayọ kẹdun pupọ. O ni ko sẹnikankan to mọ nnkan to n la kọja to fi para rẹ.

 

Leave a Reply