L’Oṣogbo, awọn TOP fẹhonu han, wọn ni kọmiṣanna ọlọpaa n ṣojuṣaaju l’Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Igun ẹgbẹ oṣelu APC nipinlẹ Ọṣun, ‘The Osun Progressives’ (TOP), ti fẹsun kan Kọmiṣanna ọlọpaa ipinlẹ naa, Wale Ọlọkọde, pe o ti di iranṣẹ Gomina Oyetọla, ko si gbaju mọ iṣẹ ipese aabo ẹmi ati dukia awọn araalu nipinlẹ Ọṣun.

Alaga wọn, Alhaji Rasaq Ṣalinṣile, Alagba Adelọwọ Adebiyi, Ọnarebu Abiọdun Agboọla atawọn agbaagba mi-in ninu TOP ni wọn fẹhonu han ni olu ileeṣẹ ọlọpaa niluu Oṣogbo.

Diẹ lara nnkan ti wọn kọ sinu awọn paali ti wọn gbe lọwọ ni ‘Ọlọpaa, ẹ ma ju wa sẹwọn mọ’, ‘Ẹtọ wa ni lati kora jọ pọ fun ipade’, ‘Ẹyin ọlọpaa, ẹ ma ṣegbe lẹyin ẹnikankan mọ’, ‘CP Ọlọkọde, iwa rẹ lo n da wahala silẹ l’Ọṣun’, ‘A ni ẹtọ lati wa ninu ẹgbẹ to ba wu wa’ ati bẹẹ bẹẹ lọ.

Ninu ọrọ Alhaji Ṣalinṣile, o ni gbogbo bi awọn alatilẹyin Oyetọla ti wọn n jẹ IleriOluwa ṣe n fitina awọn TOP ni wọn n sọ fun Ọlọkọde, sibẹ, ko gbe igbesẹ kankan lori ẹ.

Dipo ki kọmiṣanna ọlọpaa gbe igbesẹ, Ṣalinṣile sọ pe ṣe ni awọn agbofinro a maa ṣọ aṣiṣe si awọn TOP lẹsẹ, ti wọn aa si fi pampẹ ofin mu wọn.

O ni pupọ lara awọn ni ko le gbe inu ile ti wọn kọ mọ nitori ojoojumọ lawọn janduku n lọọ na wọn mọnu ile, ti awọn ọlopaa ko si ri nnkan kan ṣe si i.

Ṣalinṣile fi kun ọrọ rẹ pe tifura-tifura lawọn fi n joko ṣepade latari bi awọn janduku ṣe n ṣakọlu si awọn lojoojumọ, o ni nnkan ko ti i buru to bayii ri ko too di pe Ọlọkọde de si Ọṣun.

O waa ke si ọga agba awọn ọlọpaa lorileede yii lati gbe Ọlọkọde kuro nipinlẹ Ọṣun, nitori wọn ti n sun awọn kan ogiri bayii, ti ayọrisi rẹ si le ma dara to.

Nigba to n gba iwe ẹhonu wọn, Igbakeji kọmiṣanna ọlọpaa l’Ọṣun, Valantine Kanayo, sọ pe ileeṣẹ ọlọpaa ko si fun ẹni kan ṣoṣo, bi ko ṣe fun gbogbo araalu.

 

Leave a Reply