Ijọba ipinlẹ Ọyọ ṣẹyẹ ikẹyin fun Ọtunba Alao Akala n’Ibadan

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ti ṣapejuwe gomina ipinlẹ Ọyọ nigba kan, Ọtunba Adebayọ Alao-Akala gẹgẹ bii ojiṣẹ, ẹni to fira ẹ jin fun idagbasoke ipinlẹ naa.

Nibi itẹ ẹyẹ oku oloogbe naa, eyi tijọba ipinlẹ Ọyọ ṣe gẹgẹ bii ẹyẹ ikẹyin fun gomina tẹlẹ ọhun, lo ti sọrọ naa nileegbimọ awọn lọbalọba to wa ninu ọgba sẹkiteriati ipinlẹ naa l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindilogun, oṣu Keji, ọdun 2022 yii.

Makinde, ẹni ti Ẹnjinia Rauf Ọlaniyan ti i ṣe igbakeji rẹ ṣoju fun nibi ayẹyẹ ọhun sọ pe gbogbo ara l’Ọtunba Akala fi ṣiṣẹ fun idagbasoke ipinlẹ Ọyọ nigba to wa laye.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, ‘a mọ riri ipa ti oloogbe ko ninu idagbasoke ipinlẹ yii. Gbogbo aye lo mọ Ọtunba Akala gẹgẹ bii ẹlẹyinju aanu ati ọlọrẹ eeyan. Bẹẹ ni wọn ki i yẹ adehun, ibi teeyan ba fi adehun si pẹlu wọn lo maa ba a.” O waa ṣeleri atilẹyin ijọba rẹ fun idile oloogbe naa.

Olori ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ, Ọnarebu Debọ Ogundoyin, naa ṣapejuwe Akala gẹgẹ bii agba oṣelu to too fẹyinti gẹgẹ bii adari.

O ni, “Ọtunba Akala jẹ oloṣelu to ko gbogbo eeyan mọra. Wọn ki i ṣe adari to maa n daṣa bamubamu ni mo yo. Iyẹn lo si jẹ ki gbogbo aye fẹ wọn, ti ero tun fi pọ rẹpẹtẹ lẹyin wọn.

“Wọn ti fi itan rere balẹ loke eepẹ, orukọ wọn ko si ni i parẹ ninu iwe itan rere ni ipinlẹ yii gẹgẹ bii gomina to ṣakoso ijọba ipinlẹ yii laarin ọdun 2007 si 2011”.

Sẹnetọ to n ṣoju ẹkun idibo Ariwa ipinlẹ Ọyọ, Fatai Buhari, alaga ẹgbẹ oṣelu APC, Ọnarebu Isaac Ọmọdewu, awọn aṣofin ipinlẹ Ọyọ atawọn leekan leekan ninu ijọba ipinlẹ naa lo peju-pesẹ nibi eto ọhun.

Leave a Reply