L’Ogbomọṣọ, ọmọ ‘Yahoo’ mejilelogun ko sakolo EFCC

Faith Adebọla

Ko din ni gende mejilelogun tọwọ ajọ to n gbogun ti iwa jibiti ati ṣiṣe owo ilu mọkumọku, EFCC, ba niluu Ogbomọṣọ, ipinlẹ Ọyọ, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, wọn ni jibiti ori ẹrọ ayelujara ti wọn n pe ni ‘Yahoo Yahoo’ lawọn ọdọ naa n ṣe.

Orukọ awọn tọwọ ba yii gẹgẹ bi Alukoro ajọ Economic and Financial Crimes Commission, Ọgbẹni Wilson Uwajuren ṣe fi lede ninu atẹjade kan ni: Ibrahim Ọlajide Akintunde, Yusuf Taiye Afeez, Jimọh Idris Okikiọla, Adeyẹmọ Wariz Adegoke, Ademọla Ọlalekan Saheed, Anif Abayọmi Busayọ, Oriade Sunday Oluwatobi, Ajadi Ọpẹyẹmi, Damilọla Peter ati Akanji Blessing.

Awọn to ku ni Ọlaoluwa Felix Ogunniran, Agbei Ṣọla Peter, Tọheeb Adeagbo Tọla, Ajayi Akinyinka Umar, Ibrahim Ọpẹyẹmi Iṣọla, Samson Ṣonubi Oluwafẹmi, Oki Kayọde Oluwadahunsi, Duroṣọmọ Temitọpẹ Dickson, Akinrẹmi Ridwan Abiọdun, Ahmed Ogunlẹyẹ ati Olawore Ridwan Ọlalekan.

Uwajuren ṣalaye pe ọpọ lara awọn afurasi ọdaran ti wọn mu naa ni wọn jẹ akẹkọọ Fasiti LAUTECH, ṣugbọn kaka ki wọn dojukọ ẹkọ wọn, iwa gbaju-ẹ ni wọn n hu lori intanẹẹti, o ni inu ile kan ti wọn rẹnti niluu Ogbomọṣọ lawọn apamọlẹkun-jaye ẹda yii sa pamọ si.

Lasiko tọwọ ba wọn, ọkọ ayọkẹlẹ bọginni marun-un, ọpọlọpọ foonu igbalode alagbeeka, awọn kọmputa agbeletan, pasipọọtu irinna ofurufu atawọn iwe mi-in to lodi sofin ni wọn ba nikaawọ wọn.

Ẹka ajọ EFCC ti Ibadan to ṣiṣẹ naa ti taari awọn afurasi ọdaran yii sọdọ awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ fun iṣẹ iwadii to lọọrin, ki wọn le foju wọn bale-ẹjọ laipẹ.

Leave a Reply