Lọjọ ti a ba gbajọba Ọṣun la maa fọwọ osi juwe ile fawọn alaga kansu Oyetọla – PDP

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Adele alaga ẹgbẹ oṣelu PDP nipinlẹ Ọṣun, Dokita Adekunle Akindele, ti sọ pe bi wọn ba ṣe n bura fun Sẹnetọ Ademọla Adeleke gẹgẹ bii gomina ipinlẹ Ọṣun lọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Kọkanla, ọdun yii, naa ni yoo maa tu gbogbo awọn alaga kansu ti wọn ba wa nibẹ ka.

Ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹwaa, ọdun yii, ni ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọṣun, OSIEC, kede pe eto odibo ijọba ibilẹ yoo waye nijọba ibilẹ ọgbọn ati awọn ijọba idagbasoke agbegbe to wa nipinlẹ Ọṣun.

Wọn yoo dibo yan awọn alaga kansu, bẹẹ ni wọn yoo dibo yan awọn kansẹlọ lọjọ naa. Ẹgbẹ oṣelu mẹrindinlogun ninu awọn mejidinlogun ti a ni ni wọn si ti ṣeleri pe awọn ṣetan lati kopa ninu idibo naa.

Ṣugbọn ẹgbẹ PDP, gẹgẹ bi wọn ṣe n fọnrere lati bii oṣu meji sẹyin, sọ pe idibo naa ko ba ofin mu, ko si le duro laelae. Wọn ni ki ni ẹgbẹ oṣelu APC n wo lati ọdun yii wa ti wọn ko ṣeto idibo kansu, to waa jẹ pe lẹyin ti wọn lulẹ ninu idibo gomina ni wọn sare fẹẹ ṣeto idibo ọhun.

Akindele sọ pe awọn ko lodi si akoso to kunju oṣuwọn nijọba ibilẹ, ṣugbọn gbogbo igbesẹ ijọba gbọdọ wa nibaamu pẹlu agbekalẹ ofin.

O ni ọna lati fi owo ilu ṣofo, ati lati tubọ da rugudu silẹ ni idibo pajawiri ti ẹgbẹ APC fẹẹ ṣe naa, o si rọ awọn araalu lati ma ṣe ba wọn da si igbesẹ naa.

Akindele ṣeleri pe nigba ti asiko ba to, ijọba tuntun yoo ṣeto idibo to ba ofin mu, ohun gbogbo yoo si pada bọ sipo kaakiri ijọba ibilẹ l’Ọṣun.

Leave a Reply