Dokita Ọlaokun Ṣoyinka to jẹ ọkan ninu awọn ọmọ agba onkọwe ilẹ wa nni, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, ti sọ pe ko si ootọ kankan ninu fidio kan ti wọn n gbe kiri ori ẹrọ ayelujara pe awọn Fulani darandaran ti ya wọ ile baba naa to wa niluu Abẹokuta pẹlu ohun ija oloro, ti wọn si fẹẹ ṣe e leṣe, ti wọn tun fẹẹ ji i gbe lọ.
Ọlaokun ni oun ti fidi rẹ mulẹ pe irọ to jinna soootọ ni fidio ti wọn n gbe kiri ori ẹrọ ayelujara ọhun pe awọn Fulani ti ya wọ ile baba naa. O ni loootọ ni awọn maaluu wọ inu ilẹ Baba Ṣoyinka, ṣugbọn ko sẹnikẹni to doju ija kọ wọn tabi kọ lu wọn, tabi to gbiyanju lati ba wọn fa wahala kankan.
Ọkunrin naa waa rọ awọn eeyan ki wọn maa ṣe iwadii wọn daadaa ki wọn too maa gbe iroyin to le da wahala silẹ kiri. O ni nnkan ko rọgbọ niluu lasiko yii, a si gbọdọ ṣọra ṣe lati ma ṣe tun da kun aibalẹ ọkan to ti wa niluu lọwọlọwọ.