Ojo keji ti akekoo yii pari idanwo asekagba ni Poli Ire lo ku lojiji

Florence Babaṣọla

 

Inu ibanujẹ ni awọn ọrẹ ati akẹgbẹ akẹkọọ-binrin kan nileewe gbogboniṣe ilu Iree, nipinlẹ Ọṣun, Ọmọrinsọla Apekẹ, wa bayii, lẹyin ti wọn gbọ nipa iku ojiji to pa a.

Ẹka to n kọ nipa kokoro aifojuri, iyen Microbiology Department, la gbọ pe Apekẹ Ade, gẹgẹ bi wọn ṣe maa n pe e, wa, ọjọ Tusidee lo si kọ idanwo rẹ to kẹyin.

Lasiko ti wọn n ṣedanwo ọhun lọwọ la gbọ pe ara rẹ ko kọkọ ya nitori alaisan foni-ku-fola-dide ti won n pe ni (sickle cell) ni tẹlẹ, wọn gbe e lọ sileewosan inu ọgba, nibẹ ni wọn ti tọju ẹ, to si ṣedanwo rẹ pari nibẹ.

Lẹyin toun atawọn ọrẹ rẹ pari idanwo yii ni wọn loọ ṣeto ayẹyẹ awẹjẹ-wẹmu ti wọn n pe ni ‘Finalist Party’ nileetura kan fun aṣeyọri ti wọn ṣe lẹnu ẹkọ wọn, ti onikaluku si pada sile.

Laaarin oru la gbọ pe aisan naa tun deede kọ lu u, to si nilo ki wọn gbe ẹnjinni ti wọn fi n mi si i nimu, ṣugbọn aisi ẹnjinni naa lawọn ileewosan to wa niluu Iree ṣakoba pupọ, lẹyin wakati diẹ lo si jade laye.

Kayeefi lo jẹ fun awọn ẹgbẹ rẹ nigba ti wọn gbọ laaarọ Ojoruu, Wesidee, pe ọmọbinrin to n fo siwaju-sẹyin pẹlu idunnu lana-an ti gbekuru jẹ lọwọ ẹbọra kilẹ too mọ.

 

 

Leave a Reply