Loootọ, loootọ, o yẹ ki olori awọn EFCC yii ṣẹwọn!

 Nigba ti Adajo Chizoba Oji dajọ pe ki awọn ọlọpaa tete mu olori awọn EFCC, Abdul Rasheed Bawa, ko si la a mọ ẹwọn kia, gbogbo ilu lọrọ naa ya lẹnu. Adajọ yii ko tilẹ jẹ ki ọrọ ẹjọ naa ru ẹnikẹni loju, o ni ọgba ẹwọn Kuje ni ki wọn ju maanu naa si, ko wa nibẹ ko maa jẹwa, titi ti wọn yoo fi tun pade nile-ẹjọ nipari oṣu yii.  Adajọ yii paṣẹ fun ọga ọlọpaa patapata pe ko ma fi egbo ṣe egbo ile o, ko yaa tete da awọn ọlọpaa ẹ sita, ki wọn gbe Bawa kiakia.

Adajọ ni AbdulRasheed Bawa jẹbi ni. O Io jẹbi pe o ri ile-ẹjọ fin, nitori ko tẹle aṣẹ ti ile-ẹjọ pa. EFCC ti gbe ọkunrin kan bayii, ọga ologun ofurufu, Adeniyi Ojuawo, wọn gba mọto Range Rover to ni, wọn si fiya to wa lọwọ wọn jẹ ẹ nibi iwadii wọn. Wọn lo gba riba lọwọ awọn ileeṣẹ kan ni, pe ileeṣẹ naa lo fun un ni mọto Range Rover yii ati miliọnu lọna ogoji Naira.

Nigbẹyin, tọhun gba ile-ẹjọ lọ. Wọn fa ọrọ naa titi nile-ẹjọ, ti ile-ẹjọ fi dajọ naa ni oṣu Kọkanla, ọdun 2018, ti wọn ni Ojuawo ko ma jẹbi o, pe awọn EFCC ko lẹrii ẹjọ ti wọn pe ọkunrin naa, wọn kan n pariwo lori afẹfẹ lasan ni. Nile-ẹjọ ba paṣẹ fun EFCC pe ki wọn da mọto ọkunrin naa ti wọn gba pada fun un, nitori wọn ko lẹtọọ lati ṣe bẹẹ, ati pe gbogbo ohun ti wọn ṣe pata lo lodi sofin, bẹẹ ni ki wọn san ogoji miliọnu fun ọkunrin yii, nitori bi wọn ti ṣe laalasi ẹ.

Lati ọjọ naa ni awọn EFCC ti bẹrẹ etekete. Eyi owo ti wọn ni ki wọn san fun ọga ologun yii, wọn ko san an, eyi mọto ẹ ti wọn ni ki wọn da pada, wọn ko da a pada, ohun to si bi adajọ Oji ninu niyi, to fi ni nibi yoowu ti olori awọn EFCC yii ba wa, ki wọn yaa lọọ mu un, ki wọn si la a mẹwọn. Ọjọ kin-in-ni kọja, ọjọ keji tẹle e, o si to ọjọ kẹta ki awọn lọọya lati ileeṣẹ wọn too sare lọ sile-ẹjọ pada, ti wọn ko awọn iwe kalẹ pe awọn EFCC ti n mura lati sanwo ọkunrin naa, awọn si ti ṣeto pe ki wọn da mọto rẹ pada fun un.

Wọn ni olori EFCC yii ti ṣe awọn iṣẹ to yẹ ko fọwọ si, o si ti paṣẹ pe ki wọn gbe mọto onimọto silẹ, ki wọn si sanwo fun un, eto naa si n lọ lọwọ. Nidii eyi ni Adajọ Oji ba ni ki ọkunrin naa maa lọ, nitori o ti n ṣe ohun ti ile-ẹjọ ni ko ṣe, ko kan ti i yanju ẹ ni. Bo ba jẹ Bawa wa nile-ẹjọ lọjọ yii ni, tabi ti awọn eeyan ti ọrọ yii kan yoo ba tẹle ofin ni, ilẹ ọjọ ti wọn dajọ yii ko gbọdọ ṣu ti wọn yoo fi mu Bawa, ṣebi awọn ọlọpaa lo n ṣọ oun naa, ko si sibi to wa ti ọga agba ọlọpaa pata ko ni i ri i mu. Ohun to jẹ ki oun naa sare fara ṣoko niyi ti  ẹni kan ko fi ri i titi ti awọn lọọya EFCC fi lọ sile-ẹjọ, ti adajọ si yi ofin naa pada.

Ẹkọ to wa ninu ọrọ yii ni pe ko si ẹnikan to ga ju ofin lọ, ko si ẹni ti adajọ ko si le paṣẹ fun, tabi ran lẹwọn nigba to ba ti jokoo lori aga idajọ. Bi alaga EFCC ṣe tobi to yii, abẹ ofin lo wa, ko si gbọdọ ṣe ohun kan to lodi sofin. Ṣugbọn oriṣii aburu ni awọn ti wọn n pe ara wọn ni agbofinro yii maa n ṣe, wọn a si deede maa fiya jẹ araalu. Ohun to ṣe yẹ ki Bawa ṣẹwọn ẹ ree, koun naa ri ohun toju awọn ti EFCC ba fiya jẹ maa n ri, o yẹ ki wọn ti ṣu u rugudu ki wọn sọ ọ si ọgba ẹwọn Kuje, bo tilẹ jẹ ọjọ meji ko lo ninu akolo irin. Eyi yoo jẹ ko mọ ohun ti oju ẹlẹwọn n ri, yoo si jẹ ko mọ idi ti wọn ko fi gbọdọ fiya jẹ ẹnikẹni.

Nigba ti wọn dajọ lati ọdun mẹrin sẹyin, ti wọn ni ki ẹ sanwo ti ẹ ko san an, ka tiẹ waa ni owo ṣoro lati ri bẹẹ, ki lo ṣẹlẹ si mọto onimọto ti ẹ gba. Range Rover ẹni-ẹlẹni wa lori odo lati ọdun kẹrin ti adajọ ti dajọ pe ki wọn gbe e fun oni-nnkan, alaga loun kọwe, ṣugbọn mọto ko jade. Iru ileeṣẹ wo niyẹn. Awọn ti wọn n mu arufin ni Naijiria gan-an lolori arufin, nitori awọn gan-an ni wọn ko tẹle ofin. Ko si aṣẹ ti ile-ẹjọ pa fun wọn ti wọn yoo tẹle, kaka bẹẹ, wọn yoo maa fiya jẹ ẹni ti ile-ẹjọ ba da lare lori wọn ni.

Bi wọn ni ki wọn sanwo, wọn ko ni i san an, bi wọn ni ki wọn gbe ohun olohun fun un, wọn ko ni i gbe e fun un, wọn yoo maa fi eni donii, wọn yoo maa fi ọla dọla, titi ti ọrọ yoo fi su tọhun, ti yoo jokoo sibi kan, tabi ti iku yoo pa a. Ohun to ṣe yẹ ki olori awọn EFCC  ṣẹwọn ree, nitori bo ba ṣẹwọn, yoo jẹ ẹkọ fawọn ọmọọṣẹ rẹ, bẹẹ lawọn agbofinro to ku naa yoo ti ọwọ ọmọ wọn bọ aṣọ. O dun-un-yan pe adajọ ko jẹ ki Bawa ṣẹwọn yii, ohun ti iba tun ọpọlọ gbogbo wọn ṣe niyẹn! Lati isinsinyii lọ ṣaa o, agbofinro to ba ti tapa sofin, ẹ la yẹyẹ mẹwọn, ko ju bẹẹ lọ!

Leave a Reply