Jide Alabi
Gbogbo awọn to gbọ ni ko le gba eti wọn gbọ, iyẹn nigba ti ọmọbinrin arẹwa kan ti ko ti i ju ẹni ogun ọdun lọ, Fatima, jade sita, to si sọrọ pe baba oun n ba oun lo pọ. O ni oun ko le ka iye igba ti baba to porukọ rẹ ni Usman Momoh Yusuf, to jẹ oṣiṣẹ nileewe gbogboniṣe Rufus Giwa Polythecnic, ti n ba oun lo pọ. Nitori latigba toun ti wa ni ọmọ ọdun mẹtala ni baba oun ti sọ oun di obinrin, to si maa n ba oun sun nigbakigba to ba ti wu u. Bakan naa lo ni baba yii ti n tawọn si aburo oun obinrin, to ti fẹẹ maa ba oun naa lo pọ.
Afi bii eedi lọrọ naa ri nigba ti wọn beere pe ibo ni iya rẹ wa, to si sọ pe iya oun maa n wa ninu ile, ṣugbọn ki i da si ọrọ naa, gbogbo igba ti oun ba si sọ fun un pe oun fẹẹ ba a sọ ọrọ kan ni ki i ṣetan lati tẹti si ohun ti oun fẹẹ ba a sọ.
Ọmọbinrin yii ni baba oun ti fẹẹ maa ba aburo oun paapaa lo pọ. O ni ọjọ kan wa ti ọmọ naa sọ fun mama awọn pe baba oun n fọwọ tẹ ọyan oun, ṣugbọn niṣe ni iya naa le awọn jade, ti ko sọ ohunkohun lori rẹ.
Fidio ọmọbinrin yii lo kọkọ gba igboro kan ni ọsẹ yii, nibi ti Fatimọ Usman, ẹni ogun ọdun yii, ti fẹṣun kan baba ẹ pe gbogbo igba lo maa n fipa ba oun sun, ti iya oun ko ni i sọ ohunkohun.
Alaye ti ọmọbinrin yii ṣe sinu fidio ọhun ni pe ‘‘O pẹ ti baba mi ti n ba mi sun, nigbakigba ti mo ba si ti sọ pe mi o gba fun wọn, niṣe ni wọn maa n sọ pe awọn maa pa mi. Nigba mi-in gan-an, ki wọn too ba mi sun rara, ọbẹ ni wọn maa yọ si mi. Ọpọ igba ni wọn si maa n le mi jade ninu ile lọganjọ oru ti mo ba kọ lati jẹ ki wọn ba mi lajọṣepọ.
“Lọjọ ti ere buruku yii maa bẹrẹ, niṣe ni baba mi ni ki n niṣo nisalẹ ile wa, ninu kiṣinni, iyẹn yara idana, nibẹ ni wọn ti fipa ba mi lo pọ, lọjọ yẹn naa ni wọn gba ibale mi. Ki i ṣe oju lasan tabi ọrọ ẹnu o, ada ati ọbẹ ni wọn yọ si mi, ti wọn sọ pe ti mo ba pariwo pẹrẹn, niṣe lawọn yoo pa mi danu.
“Nibi ti mo ti ko si wahala ifipabanilopọ lọwọ baba mi niyẹn o lati ọmọ ọdun mẹtala.”
Fatima fi kun un pe oun ko loyun fun baba naa ri, nitori o maa n ṣakiyesi asiko ti oun ba n ṣe nnkan oṣu, ki i si i ṣe e lasiko igba ti oyun le duro si oun lara.
Nigba ti wọn beere mama rẹ ati ibi to maa n wa nigba ti baba rẹ ba fẹẹ huwa buruku naa, o ni, ‘‘Inu ile ni iya mi maa n wa ti baba mi ba n hu iwa buruku yii, bi wọn ba le mi jade paapaa, ara ki i ta wọn, wọn ki i si i bikita rara boya mo wa ninu ile tabi ita ni mo sun, nitori ita ni mo maa n sun lọjọ ti wọn ba ti le mi jade.’’
Bakan naa lo tun fi kun un pe nigba ti baba naa bẹrẹ si i ba oun sun ni aṣiri ohun to gbe ẹgbọn awọn kuro nile to fi dẹni to n gbe ni Ọwọ, nipinlẹ Ondo, ṣẹṣẹ n ye oun. O ni ṣadeede lo kuro nile, ti ki i yọju sile awọn mọ.
Fatimọ ni ohun ti baba awọn n foju oun ri yii ti mu oun beere lọwọ iya oun lọpọ igba pe ṣe baba naa lo bi oun ati aburo oun kekere to maa n fọwọ tẹ lọmu yii abi oun kọ, ṣugbọn ti iya awọn ni ki awọn gbẹnu dakẹ.
Nigba ti awọn akọroyin bi i idi ti ko fi sọrọ yii sita latijọ yii lo sọ pe gbogbo ẹ pata lo wa lọwọ Ọlọrun, nitori oun ko ni in lọkan lati tu aṣiri ọrọ ọhun sita, bo tilẹ jẹ pe ọpọ igba loun ti halẹ mọ baba naa pe oun yoo pariwo ẹ faraye.”
O ni lọdun 2018 ni baba naa ṣeleri pe oun yoo tu oun silẹ ti ko ni i siru nnkan bẹẹ laarin awọn mọ, ṣugbọn to tubọ tẹ siwaju ninu iwa idọti yii. O ni, “Nigba ti wọn tun fẹẹ bẹrẹ iwa oṣi yii lọdun 2020 ni mo yari mọ wọn lọwọ pe ti wọn ko ba tu mi silẹ, mo ṣetan lati gba ara mi lọwọ wọn, eyi to mu mi kegbajare sita bayii.
Fatimọ sọ pe ni gbogbo igba ti oun ba ti yari mọ baba yii lọwọ pe oun ko ṣe, niṣe lo maa n le oun sita, ti mama oun ko si ni sọ ohunkohun.
Arabinrin Diamond Mary, ẹni ti i ṣe ẹgbọn Fatima ninu ọrọ tiẹ sọ pe nigba ti Fatima sa kuro nile, ọpọ ọjọ lawọn fi wa a, ko too di pe oun ri i lọjọ kan to waa ba oun nile. O ni, nigba ti oun si tẹ ẹ ninu daadaa nipa ohun to mu un kuro nile lo jẹwọ foun pe niṣe ni baba oun maa n fipa ba oun laṣepọ.
O ni boun ṣe gbọrọ yii loun ti lọọ koju Usman Momoh Yusuf ti wọn fẹsun kan yii, ti awọn ọlọpaa to wa ni Ọtapẹtẹ, niluu Ọwọ, ipinlẹ Ondo, si ti bẹrẹ iṣẹ wọn.
Ni bayii, ileeṣẹ ọlọpaa ti mu Usman Momoh Yusuf ti ọmọ yii fẹsun kan pe o n ba oun laṣepọ, lẹyin ti baba naa ti kọkọ sa lọ nigba ti okiki ohun to ṣe yii gba igboro kan.
Agbẹnusọ fun ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Ọndo, Tee-Leo Ikoro, fidi ẹ mulẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọse yii pe ọwọ ti tẹ Usman Momoh Yusuf to n ṣere buruku pẹlu ọmọ ẹ yii.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa ti bẹrẹ iwadii lori ẹsun ti ọmọ yii fi kan baba ẹ. O ni, “Loju-ẹsẹ ti fidio yẹn ti wa nigboro ni ọkunrin naa ti sa lọ, ṣugbọn ọwọ ti tẹ ẹ bayii, bẹẹ lo ti n ran wa lọwọ nileeṣẹ ̀ọtẹlẹmuyẹ niluu Akurẹ lori ẹsun ti ọmọ ẹ fi kan an.”
ALAROYE gbọ pe iyawo gomina ipinlẹ Ondo, Betty Akeredolu paapaa ti gbọ si ọrọ naa.
Akeredolu sọ pe ohun to baayan lọkan jẹ ni, bẹẹ lo tun jẹ ọrọ ti ko ba eti mu, nigba ti oun gbọ gbogbo alaye ti ọmọ naa ṣe lori fidio ti awọn eeyan n pin kiri yii. Bẹẹ lo sọ pe iru Ọgbẹni Momoh Yusuf naa ko yẹ lẹni to gbọdọ maa gbe lawujọ awọn eeyan gidi.
Akeredolu sọ pe ohun to baayan lọkan jẹ ni, bẹẹ lo tun jẹ ọrọ ti ko ba eti mu, nigba ti oun gbọ gbogbo alaye ti ọmọ naa ṣe lori fidio ti awọn eeyan n pin kiri yii. Bẹẹ lo sọ pe iru Ọgbẹni Momoh Yusuf naa ko yẹ lẹni to gbọdọ maa gbe lawujọ awọn eeyan gidi.