Sinima ere ori itage ni wahala to n lọ laarin oṣere ori itage ilẹ wa ti wọn n pe ni Baba Ijẹṣa ati oṣere mi-in ti wọn n pe ni Damilọla Adekọya ti gbogbo eeyan mọ si Princess to fẹsun kan Baba Ijẹṣa pe o fipa ba ọmọ ti wọn fi ṣe oun laaanu lẹyin ti ọmọ oun ku lo pọ da bayii. Eyi ko sẹyin bi lọọya Baba Ijẹṣa ti wọn pe orukọ rẹ ni Akin Ọlafẹsọ ṣe jade sita, to si ni oun ti ṣetan lati gbẹjọ Baba Ijẹṣa ro nile-ẹjọ.
Ninu ọrọ kan ti wọn ni ọkunrin naa sọ to n ja ranyin lori ẹrọ ayelujara bayii lo ti sọ pe, ‘‘Onibaara mi, iyẹn (Baba Ijẹṣa), ti ni ajọṣepọ pẹlu Princess tẹlẹtẹlẹ, ṣugbọn Princess ko fura titi ti onibaara mi fi lo anfaani bo ṣe sun mọ obinrin naa to fi wọle si ọmọ ti o gba tọju lara, to si ṣe e baṣubaṣu.
‘‘Nigba ti oṣere ti wọn n pe ni Princess yii gbọ eleyii lo pinnu lati dẹ okun fun Baba Ijẹṣa lati kọ ọ lẹkọọ ti ko ni i gbagbe laye rẹ.
‘‘Ṣugbọn awa naa ti ṣetan lati pade Princess ni kootu.’’ Akin Ọlafẹso to jẹ lọọya Baba Ijẹṣa lo sọ bẹẹ.