A ti sin awọn Fulani mejilelogoji ta a ko l’Okitipupa jade nipinlẹ Ondo- Adelẹyẹ

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Alakooso ẹsọ Amọtẹkun nipinlẹ Ondo, Oloye Adetunji Adelẹyẹ, ni awọn ti da awọn Fulani darandaran bii mejilelogoji tí wọn ko niluu Okitipupa lalẹ Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja, pada si ipinlẹ olukuluku wọn.

O ni ijọba pinnu lati gbe igbesẹ naa nitori aabo ẹmi ati dukia awọn eeyan ipinlẹ Ondo.

Oloye Adelẹyẹ ni ijọba fidi rẹ mulẹ ninu iwadii ti wọn ṣe lẹyin ti wọn lọọ ko awọn bororo ọhun niluu Okitipupa pe bi wọn ṣe deedee ya bo agbegbe naa le ṣe akoba nla fun eto aabo ẹmi awọn eeyan.

Awọn Fulani bii mejilelogoji ọhun ti wọn wa lati ipinlẹ Jigawa ati Kano lo ni wọn ko ri ọrọ gidi sọ nigba ti awọn n fọrọ wa wọn lẹnu wo lori bi wọn ṣe de ilu Okitipupa.

O ni ohun ti ọpọ wọn n tẹnu mọ ni pe, ileeṣẹ kan lo ko awọn wa si ipinlẹ Ondo lati waa da awọn lẹkọọ gẹgẹ bii ẹṣọ alaabo.

Pupọ ninu awọn ajoji ọhun lo ni wọn ko tilẹ le sọ ni pato idi wọn fi ba ara wọn nibi ti awọn ẹsọ Amọtẹkun ti lọọ ko wọn, o ni ṣe ni wọn n wo suu bii ẹni pe ohun to n sẹlẹ ko ye wọn rara.

Oloye Adelẹyẹ ni awọn ti ranṣẹ pe ileesẹ aladaani kan ti wọn lo ṣe agbatẹru bi awọn Fulani ọhun ṣe wọ ilu, o ni alaye ti wọn ṣe ni pe awọn eeyan kan lo ko wọn ranṣẹ si ọdọ awọn ki wọn le kẹkọọ nipa iṣẹ ẹṣọ alaabo.

Ọrọ awọn Fulani ọhun ti ko dọgba pẹlu awọn to ṣe atọna bi wọn ṣe wọlu lo ni ijọba ro papọ ti wọn fi pinnu lati sin wọn kuro nipinlẹ Ondo lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.

Oloye waa fawọn eeyan lọkan balẹ lati maa ba iṣẹ wọn lọ, ki wọn si maa fi ohunkohun ti wọn ba ṣakiyesi pe o n dunkooko mọ ẹmi ati dukia wọn to awọn ẹsọ alaabo leti.

Leave a Reply