Oṣere tiata, Lizzy Anjọrin, bimọ tuntun s’Amẹrika

Jide Alabi

Idunnu ti ṣubu layọ fun ọkan ninu awọn oṣere ilẹ wa, Lizzy Anjọrin, pẹlu bi oṣere naa ṣe bi ọmọ tuntun jojolo si orileede Amẹrika.

Ilu kan ti wọn n pe ni Miami ni Amẹrika, lo bi ọmọ naa si lọjọ kin-in-ni, oṣu karun-un yii.

Ninu fidio kan ti oṣere naa gbe jade lo ti fi aworan igba to wa ninu oyun han. O kọ ọ sibẹ pe ‘O ti jẹrii ara rẹ ninu aye mi, mo si waa ri daju bayii pe o jẹ olotitọ ju ki o ja ni kulẹ lọ.’

Bakan naa lo kọ ọ sori ikanni rẹ pe, ‘‘Ọba Aṣekan ma ku ti ṣe e fun mi. Ọba to maa n da eeyan lẹjọ gẹgẹ bi inu rẹ ba ṣe ri, ti ki i ṣe bi awọn eeyan ba ṣe da a lẹjọ.

‘‘Ọba pẹgan mi rẹ ti pa ẹgan mi rẹ patapata.

Ẹ dara pọ mọ wa lati ki wa ku oriire ojurere Allah ti a ri pẹlu bo ṣe tun bukun fun wa. Opẹ ni ọrọ wa ja si.’’

Ṣugbọn bi awọn kan ṣe n ki oṣere yii ku oriire lawọn kan n sọ pe ki eeyan naa waa sọ pe ki i ṣe Amẹrika lo bimọ si, ile alagbo ni, gẹgẹ bo ṣe n bu Toyin Abraham nigba ti oṣere naa bimọ, to si n sọ pe ile alagbo lo bimọ si.

 

Leave a Reply