Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Ọjọ Aje, Monde, ọṣẹ yii, ni Oludasilẹ ẹgbẹ to n ja fun ẹtọ awọn ọmọ Musulumi (MURIC), Ọjọgbọn Ishaq Akintọla, sọrọ lori fọnran fidio to gba ayelujara, nibi ti wọn ti lu awọn ọmọ-kewu lalubami, o ni ohun ti awọn ile-kewu naa ṣe lo ba ilana sẹria mu lati le kọ awọn ọmọ lẹkọọ.
Akintọla sọ pe ta a ba sọ pe ijiya naa ti pọ ju fun awọn akẹkọọ naa, ka tun ranti pe awọn obi ọmọ ni wọn mẹsun lọ si ile-kewu pe ki awọn aafa da sẹria fun awọn ọmọ wọn latari pe wọn lọọ huwa ko tọ nibi ayẹyẹ ọjọ ibi ti wọn lọ, wọn mu ọti, wọn tun n tu ọti sira wọn lara, eyi to ta ko ofin ilana ẹṣin ọmọlẹyin Anọbi. O tẹsiwaju pe awọn tun wo fọnran fidio miiran, nibi ti ọkan ninu awọn ọmọ-kewu naa ti jẹwọ pe loootọ ni awọn mu ọti, ti awọn si n tu ọti si ara awọn lara, leyii ti ko yẹ ki a ba ọmọ Musulumi nibẹ, abi bawo ni wọn ṣe n pin itan aja to n kan Imaamu.
O fi kun ọrọ rẹ pe ile-kewu lo ti yẹ ki wọn kọ wọn ni irufẹ ẹkọ bẹẹ, ti wọn o ba kọ wọn ni ile-kewu, nibo ni wọn aa ti ri ẹkọ naa gba. Akinọla ni o ba ni lọkan jẹ jọjọ tori pe gbogbo awọn iṣoro ta a n koju lorileede Naijiria lonii, lọwọ awọn obi lo ti wọ wa latari pe wọn o ba awọn ọmọ wi mọ ti wọn ba huwa ko tọ, ọwọ ni wọn fi n ra wọn lori.
O ni kawọn ọmọ Naijiria ya oju wọn daadaa, ki wọn mọ irufẹ ibi ti awọn alasẹ ile-kewu ọhun ti wa, ki wọn si mọ pe ti wọn o ba kọ awọn ọmọ naa lẹkọọ bẹ, awọn miiran ninu wọn yoo tun maa lọ si pati, ti wọn aa si maa lọọ ṣe bo ṣe wu wọn tori pe ẹṣin iwaju ni tẹyin wọn yoo maa wo sare, ati pe gbogbo ipaniyan, ijinigbe, ati ifipa ba ni lo pọ to n ṣẹlẹ lapa loke ọya orile-ede yii, ọjọ kan lo bẹrẹ, ti a ko ba si ti kekere pẹka iroko to ba dagba tan aa maa gbẹbọ lọwọ ẹni.
Fun idi eleyii, ki i ṣe London ni a wa, nibi ti ọmọ ọdun marun-un yoo ti maa fi ọlọpaa mu iya rẹ to ba ba a wi. Ẹgbẹ naa rọ olugbe ipinlẹ Kwara lati jẹ ki ijọba ipinlẹ Kwara ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ naa nipa pe ki wọn pe obi awọn ọmọ ati awọn alaṣẹ ile-kewu ọhun papọ lati wijọ.