Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun pe O mu mi pada sile laaye – Tinubu

Faith Adebọla, Eko

Ṣinkin bii ẹni jẹ tẹtẹ oriire ni inu agba oloṣelu ilu Eko to ti figba kan jẹ gomina ipinlẹ Eko, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, n dun lasiko yii, pẹlu bi baba naa ṣe ni kawọn eeyan maa ba oun dupẹ lọwọ Ọlọrun pe o ṣọ oun lọ, o si mu oun pada bọ si Naijiria laaye, o lorin ọpẹ lo wa lẹnu oun.

Tinubu, Aṣaaju ẹgbẹ oṣelu APC lapapọ, sọrọ yii lọsan-an ọjọ Aiku, Sannde, nibi apejẹ pataki kan ti ijọba Eko ṣe fun un lati ki i kaabọ. Ile ijọba ipinlẹ Eko to wa lagbegbe Marina, l’Erekuṣu Eko lọhun-un, lapejẹ naa ti waye.

Tinubu ni, “Ẹ ma jẹ ki n tan yin, o ri bakan lara mi ti mo ba n ronu nnkan ti mo la kọja lasiko iṣẹ abẹ ti mọ lọọ ṣe si ojugun mi.

“Ṣugbọn inu mi dun pe mo pada sile layọ, Ọlọrun lo n fun-un-yan ni iwalaaye, oun nikan naa lo si le gba a.”

Ọpọ awọn oloṣelu nipinlẹ Eko lo pesẹ sibi apejẹ ọhun. Lara wọn ni Gomina Eko, Babajide Sanwo-Olu ati iyawo rẹ, Abilekọ Ibijọkẹ Sanwo-Olu, Igbakeji Gomina Eko, Ọbafẹmi Hamzat ati iyawo rẹ, Olurẹmi Hamzat, igbakeji gomina Eko tẹlẹ ri, Abilekọ Idiat Adebule, Olori awọn aṣoju-ṣofin l’Abuja, Ọnarebu Fẹmi Gbajabiamila, Olori awọn aṣofin Eko, Ọnarebu Mudashiru Ọbasa, Sẹnetọ Ọlamilekan Solomon ati awọn mi-in.

Ṣaaju, lọjọ Satide, ni Tinubu ti fi atẹjade kan lede lati dupẹ lọwọ gbogbo awọn ololufẹ rẹ, awọn oloṣelu ẹlẹgbẹ rẹ, ati ọpọ eeyan ti wọn ṣaaro rẹ nigba to fi rinrin-ajo lọ si London, lorileede United Kingdom, fun itọju iṣegun ọhun. Oṣu mẹta o din ọjọ diẹ ni baba naa fi wa lọhun-un latari iṣẹ abẹ ti wọn ṣe fun un.

Atẹjade kan ti wọn fi lede lati ọfiisi Akọwe iroyin rẹ sọ pe baba naa dupẹ lọwọ Aarẹ ilẹ wa, Muhammadu Buhari, Gomina ipinlẹ Eko, Sanwo-Olu, ati ọgọọrọ awọn eeyan pataki pataki ti wọn tẹkọ leti lati ṣabẹwo si i lasiko to fi wa lẹyin odi naa.

O tun dupẹ lọwọ awọn ti wọn ko wa, ṣugbọn ti wọn ṣadura, ati awọn ti wọn pe e lori aago pẹlu.

Tinubu ni o pọn dandan foun lati pada sile, yatọ si pe ara oun ti ya daadaa, o ni oun ṣi ni lati ko awọn ipa pataki kan ninu eto aabo ati oṣelu orileede wa, ki oun si fọwọsọwọpọ lati tubọ mu ki Naijiria bori awọn iṣoro to n kọju rẹ lasiko yii.

Leave a Reply