Gbogbo ẹyin tẹ ẹ ti gba abẹrẹ Koro, ẹ si tẹsiwaju lati maa lo ibomu yin o – ijọba Kwara

 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

Ọjọ Ẹti, Furaidee, opin oṣe to kọja yii ni ijọba ipinlẹ Kwara, labẹ iṣejọba Gomina Abdulrahman Abdulrasaq, ṣekilọ pe ki gbogbo awọn to ti gba abẹrẹ ajẹsara Korona ṣi tẹsiwaju lati maa lo ibomu wọn, ki wọn si maa tẹle ofin itakete si ra ẹni lawujọ ọpọ ero

Akọwe agba ẹgbẹ to n ri si idagbasoke eto ilera alabọọde nipinlẹ Kwara, Dokita Nusirat Elelu, lo ṣe ikilọ yii nibi ipade akọroyin kan ti wọn ṣe ninu ọgba ileewe giga Fasiti Ilọrin, nipinlẹ Kwara, lọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọṣẹ yii. O ni ki awọn araalu maa lo ọsẹ apakokoro lawọn ileeṣẹ gbogbo, ki wọn maa fọwọ loore-koore, ki wọn tun maa jinna si awujọ ọpọ ero.

O tẹsiwaju pe iroyin ti awọn kan n gbe kaakiri nipa abẹrẹ ajẹsara Korona ki i ṣe otitọ, tori pe abẹrẹ ajẹsara ọhun fi ni lọkan balẹ dọba, idi ni pe ajọ to n ri si eto ilera lagbaye ati ajọ NAFDAC yẹ abẹrẹ naa wo, ti wọn si dan an wo pẹlu, ti wọn fontẹ lu u pẹlu. O waa parọwa si gbogbo olugbe ipinlẹ Kwara ki wọn ma lero pe ti wọn ba ti gba abẹrẹ ajẹsara Koro, wọn o nilo lati maa lo iboju ati ibomu wọn mọ, ki wọn tẹsiwaju ninu lilo rẹ, tori pe arun Korona ko ti i kasẹ nilẹ tan.

Leave a Reply