Faith Adebọla
Afaimọ ni ki Aarẹ Muhammadu Buhari ma kawọ pọnyin rojọ laipẹ, pẹlu bi awọn eekan agbẹjọro meji kan nilẹ wa, Oloye Fẹmi Falana ati Amofin agba Ẹbun-Olu Adegboruwa, ṣe kede pe Aarẹ Buhari ti ṣẹ sofin pẹlu iyansipo yii, awọn si maa ba a fa a nile-ẹjọ.
Falana ti i ṣe alaga ẹgbẹ ASCAB, sọ ninu atẹjade to fi sode fawọn oniroyin l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii lori bi Aarẹ ṣe yan awọn mẹrin tuntun sipo olori awọn ologun ilẹ wa lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja, pe ko tọna, ko si bofin mu, bi iyansipo naa ṣe waye lai jẹ pe o kọkọ dabaa orukọ naa ṣọwọ sile aṣofin agba ilẹ wa (Senate), lati yiri wọn wo, ki wọn si fọwọ si i.
Atẹjade naa sọ lapa kan pe: “Iyansipo awọn olori ologun lai gba ifọwọsi ileegbimọ aṣofin ti daṣa lati ọdun 1999, eyi lo si mu ki Amofin agba Festus Keyamọ wọ Aarẹ Goodluck Jonathan (nigba yẹn) lọ sile-ẹjọ giga apapọ lọdun 2008, ninu iwe ipẹjọ ti nọmba rẹ jẹ FHC/ABJ/CS/611/2008.
“Ile-ẹjọ gbe idajọ kalẹ lọjọ keji, oṣu keje, ọdun 2013, pe ko bofin mu rara, ko si lẹsẹ nilẹ, ofuutufẹẹtẹ ni, bi Aarẹ ba da nikan yan awọn olori ologun fun orileede lai gba ifọwọsi ileegbimọ aṣofin. Adajọ Adamu Bello ni aṣa naa ta ko isọri okoolerugba o din meji (218) iwe ofin ilẹ wa (constitution) ati isọri kejidinlogun iwe ofin to ṣagbekalẹ awọn ileesẹ ologun (Armed Forces Act).
“Tori idajọ naa peye, o tẹwọn, ko si ṣee ja ni koro, ni ko jẹ kijọba pẹjọ ko-tẹ-mi-lọrun lori ẹ, eyi to tumọ si pe ilana to yẹ ki wọn tẹle niyẹn, bo ṣe wa ni isọri ọọdunrun o din mẹtala iwe ofin ilẹ wa.”
Ohun ti Amofin agba Ẹbun-Olu Adegboruwa sọ lọfiisi rẹ l’Ọjọbọ nipa iyansipo ti aarẹ ṣe ọhun ko yatọ si ti Falana, awọn mejeeji lo sọ pe idajọ to ti kọkọ waye lori ọrọ yii ko yọnda fun Aarẹ lati da nikan pa a, ko si da nikan kun un, to ba dọrọ yiyan awọn olori ologun sipo.
Ni bayii, awọn amofin agba naa ti ke si Aarẹ lati ṣatunṣe kiamọsa, ki wọn taari orukọ awọn mẹrẹẹrin sileegbimọ aṣofin, ki wọn si so iyansipo ti wọn ṣe yii rọ na, titi tawọn aṣofin yoo fi fọwọ si i tabi ta ko o.
Gẹgẹ bi Ajọ Akoroyinjọ ile wa ṣe wi, wọn ni (Falana ati Adegboruwa) ni ti Buhari ko ba gbe igbesẹ yii, aa jẹ pe awọn pẹlu ẹ yoo jọ de ile-ẹjọ laipẹ niyẹn.