Lori ọrọ hijaabu, awọn ọdọ kọ lu ṣọọṣi ‘The Apostolic’ n’llọri

 

Gbogbo ferese gilaasi ileejọsin The Apostolic, to wa ni Sabo-Oke, niluu Ilọrin, ni wọn fọ yangan yangan.

Nibi tọrọ ọhun de duro bayii, afaimọ ki ija ẹsin ma ṣuyọ laarin awọn Musulumi ati Kristẹni nipinlẹ Kwara, paapaa, niluu Ilọrin.

Lọsẹ to kọja yii lawọn kan ya bo ileejọsin ati ileewe Onitẹbọmi, First Baptist, to wa ni Surulere, niluu Ilọrin, nibi ti wọn ti rọjo okuta lu gbọngan nla kan to wa niluu ọgba ileejọsin naa, ti wọn si ja geeti abawọle ileewe Baptist to wa lẹgbẹẹ ṣọọṣi naa lulẹ.

Bo tilẹ jẹ pe ijọba loun n sa ipa lati pana wahala naa, ṣugbọn awọn eeyan kan, paapaa Kristẹni, ti bẹnu atẹ lu igbesẹ tijọba gbe lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ to kọja yii, lati fi tipa tikuuku ṣi awọn ileewe to jẹ tajọ ọmọlẹyin Kristi.

Leave a Reply