Lori ọrọ ti ko to nnkan, Idowu gun ẹgbọn rẹ lọbẹ pa n’Igbọkọda

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

 

Ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo ti fi pampẹ ofin gbe ọmọbinrin kan, Ruth Idowu Biletiri, lori ẹsun gigun ẹgbọn rẹ, Kẹhinde Biletiri, lọbẹ pa niluu Igbọkọda nijọba ibilẹ Ilajẹ l’Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja.

Gẹgẹ ba a ṣe gbọ, o to bii ọjọ meji sẹyin ti obinrin ẹni ọdun mẹtadinlogun ọhun ti kuro nile lai dagbere ibi to n lọ fun ẹnikẹni.

Oloogbe ọhun nikan lo ba nile lasiko to pada wọle l’Ọjọbọ, Tọsidee, dipo ti iba si fi ṣalaye ara rẹ fun un nigba ti iyẹn n beere ibi to gba lọ ti ko fi wale waa sun, ile idana lo mori le, nibi to ti mu ọbẹ eyi to fi gun ẹgbọn rẹ leralera.

Awọn araadugbo kan la gbọ pe wọn gbiyanju ati gbe ọmọkunrin yii lọ sile-iwosan boya wọn ṣi le ri ẹmi rẹ ra pada, ṣugbọn wọn ko ti i debẹ to fi dakẹ mọ wọn lọwọ.

Kiakia lawọn ọlọpaa ilu Igbọkọda ti fi pampẹ ofin gbe aburo rẹ ti wọn fẹsun kan pe o gun un pa.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ yii mulẹ, Alukoro ileesẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Tee-Leo Ikoro, ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori rẹ.

 

 

Leave a Reply