Maṣinni ti wọn fi n ṣe ọṣẹ lo ge akẹkọọ Fasiti Ibadan yii si wẹwẹ nibi to ti n ṣiṣẹ

Titi di ba a ṣe n sọ yii lawọn eeayn ṣi n tara ikunlẹ abiyamọ lori iku buruku to pa ọdọmọkunrin ẹni ọdun mọkanlelogun kan, Gbadebọ Richard, to jẹ akẹkọọ ọlọdun kẹta nileewe giga Fasiti Ibadan. Maṣinni to fi n ṣiṣẹ lo ge e si meji, o si ku nibi to ti n ṣiṣẹ aje lati ri owo lasiko ti ileewe wa lọlude Korona niluu Ibadan.

ALAROYE gbọ pe ileeṣẹ awọn Ṣaina kan ti wọn n pe ni Hankel Nigeria Limited, ti wọn n ṣe ọṣẹ ifọṣọ WAW atawọn oriṣiiriṣii nnkan mi-in to wa ni Oluyọle, niluu Ibadan, ni ọmọkunrin yii lọ nitori ileewe to wa nisinmi Korona lati ṣiṣẹ.

Ọkan ninu awọn ọrẹ rẹ ṣalaye pe ẹka ibi ti wọn ti n ṣe ọsẹ abufọ ti wọn n pe ni (detergent) ni Gbadebọ ti n ṣiṣẹ. Iṣẹ alẹ ni wọn lo ṣe lọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii ti iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ.

Wọn niṣe ni ọmọkunrin naa lọọ bu ohun eelo ti wọn fi n ṣe ọṣẹ naa sinu maṣinni, lasiko to n bu u sinu rẹ ni apo ti ohun eelo ọṣẹ naa wa ninu rẹ kọ maṣinni naa, nibi to ti n gbiyanju lati yọ ọ lo ti wọ inu maṣinni naa, ti iyẹn si ge e si meji lọgbọọgba, to si kun un si wẹwẹ bii ẹran.

Awọn tiṣẹlẹ naa ṣoju wọn sọ pe awọn yooku ko tete mọ pe nnkan ti ṣẹlẹ si Gbadebọ, afigba ti ọsẹ to n jade lodikeji lọhun-un ti wọn fẹẹ rọ sinu ọra jẹ kiki ẹjẹ, eyi lo mu ki wọn lọọ wo maṣinni to n po ọsẹ pọ naa, to si jẹ pe ẹsẹ ọmọkunrin yii ni wọn ri nilẹẹlẹ nibẹ.  Ilaji ara Gbadebọ ni wọn ni maṣinni naa ti lọ lubulubu. Ilaji ara to ku to ti run jegejege la gbọ pe wọn gbe fun awọn obi rẹ ti wọn lọọ gbe si ile igbokuu-si.

Ohun to dun awọn eeyan, paapaa awọn akẹkọọ ẹgbẹ Gbadebọ, lori ọrọ yii ni iha ‘ko kan mi’  ti awọn to ni ileeṣẹ naa kọ si iṣẹlẹ ọhun. Wọn ni awọn eeyan naa ko tilẹ bikita lati ranṣẹ ibanikẹdun, tabi ki wọn ṣe abẹwo si ẹbi ọmọkunrin naa.

Eyi lo mu ki awọn ẹgbẹ akẹkọọ fi ẹhonu wọn han lori iṣẹlẹ yii, ti wọn si bu ẹnu atẹ lu awọn ileeṣẹ naa.

Lẹyin eyi ni awọn ileesẹ Hankel fi atẹjade kan sita, nibi ti wọn ti tọrọ aforiji pe o pẹ ki awọn too gbe igbesẹ lori iṣẹlẹ naa. Wọn ṣeleri lati ṣe iwadii to yẹ lori rẹ.

Leave a Reply