Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
Yiyan bii ologun tawọn agunbanirọ n ṣe laaarọ Ọjọruu, ọjọ kọkanla, oṣu kẹjọ yii, duro lojiji ninu ọgba wọn to wa ni Ṣagamu, nipinlẹ Ogun, nigba ti maaluu kan ja wọ inu ọgba naa, to si bẹrẹ si i le awọn eeyan to wa nibẹ kiri.
Ninu fidio kan to gun ori ayelujara l’Ọjọruu naa lawọn eeyan ti mọ ohun to ṣẹlẹ, nigba ti maaluu ti wọn ni digbolugi ni ọhun, deede ja wọle, to si n ṣe bii ko ri ẹnikan kan pa.
Kia ni awọn agunbanirọ atawọn ṣọja to n kọ wọn lẹkọọ nipa yiyan bii ologun naa yaa dawọ duro, wọn sa asala fun ẹmi wọn ki wọn too kapa maaluu naa, ti wọn mu un kuro ninu ọgba yii.
Alukoro awọn agunbanirọ nipinlẹ Ogun, Abilekọ Florence Takum, fidi iṣẹlẹ yii mulẹ. O ni loootọ ni maaluu ja wọgba nigba tawọn n ṣe pareedi lọwọ, ṣugbọn Ọlọrun ko jẹ ko ṣe ẹnikẹni leṣe ti wọn fi mu un kuro ninu ọgba naa.