Stephen Ajagbe, Ilorin
Ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Kwara ni ọwọ awọn ti tẹ afurasi ajinigbe, Kazeem Mohammed, to n gbe niluu Patigi, nipinlẹ Kwara, pẹlu awọn ẹgbẹ rẹ mẹta; Mohammed Chatta, Jimoh Abdulateef ati Madi Jeremiah, ti wọn pa Olokoṣẹ Oluwaṣọla Ojo, ti wọn si ge ẹya ara rẹ wẹlẹwẹlẹ lati fi ṣoogun owo.
Alukoro ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Ajayi Ọkasanmi, lo sọ eleyii di mimọ ninu atẹjade kan l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii. O ṣalaye pe Kazeem tan Ojo, o si gba ẹgbẹrun lọna ọgọfa naira (#160,000) lọwọ rẹ lati ba a ra maaluu to fẹẹ lo fun eto igbeyawo rẹ.
Lẹyin tiyẹn ko owo kalẹ loun pẹlu Kazeem jọ kuro niluu Ilọrin lọ sibi to lawọn ti maa ra maaluu, ṣugbọn lati ọjọ naa niyawo afẹsọna rẹ, Ilọri Oluwakẹmi, ati mọlẹbi rẹ ko ti gburoo rẹ mọ.
Nigba to di ọjọ kẹta, oṣu kẹta, ọdun yii, ṣadeede ni iyawo rẹ gba ipe lati ori foonu ọkọ rẹ, bo ṣe gbe ipe naa, awọn to ba a sọrọ sọ pe ajinigbe lawọn, ọkọ rẹ si wa lahaamọ, miliọnu mejila naira lo gbọdọ san to ba fẹẹ ri i laaye.
Ọkasanmi ni bi iroyin iṣẹlẹ naa ṣe de ọdọ awọn ni Ọga ọlọpaa nipinlẹ Kwara, Muhammed Bagega, ti pe fun iwadii to peye, to si paṣẹ pe ki wọn mu awọn ọdaran to ṣiṣẹ naa, ki wọn si didoola ẹmi ẹni to wa lahaamọ wọn.
O ni lasiko iwadii awọn lọwọ tẹ Kazeem Beiwa Mohammed to jẹ olori awọn ajinigbe naa niluu Patigi. Nigba tawọn ọlọpaa tẹsiwaju ninu iwadii wọn, ọwọ pada tẹ awọn ẹgbẹ rẹ.
Wọn ni lasiko tọwọ tẹ wọn, ninu wọn jẹwọ pe loootọ awọn lawọn pa Ojo, tawọn si ri oku rẹ sinu koto kan ninu igbo.
O ni nigba tawọn afurasi naa mu awọn ọlọpaa debi ti wọn ri oku rẹ mọ, awọn ri i pe wọn ti ge ori ati apa rẹ. Kazeem gan-an lo loun fẹẹ fi ṣoogun owo.
Atẹjade naa ṣalaye siwaju pe awọn afurasi naa jẹwọ pe awọn mọ-ọn-mọ tan Oloogbe naa lọ si ẹyin odi ilu Patigi ni, nibi tawọn sọ fun un pe awọn so maaluu to fẹẹ ra mọ, bawọn ṣe debẹ lawọn yinbọn pa a.
Ileeṣẹ ọlọpaa ni awọn ti gbe oku ọkunrin naa lọ si mọṣuari ilewosan ẹkọṣẹ Fasiti Ilọrin, UITH.
Ọga ọlọpaa, Mohammed Bagega, gba araalu nimọran lati maa mọ iru awọn ti wọn yoo ma ba dowo pọ, ki wọn si maa gbe pẹlu ifura, nitori pe awọn eeyan ibi pọ lawujọ.
O ni ileeṣẹ ọlọpaa yoo wọ awọn afurasi naa lọ sile-ẹjọ ni kete ti wọn ba wọle iṣẹ pada.