Magu kuro lahaamọ lẹyin ọjọ kẹwaa

Alaga ajọ to n gbogun ti ṣiṣe owo ilu basubaṣu tẹlẹ, Ibrahim Magu, ti kuro ninu ahamọ lẹyin ọjọ mẹwaa to ti wa nibẹ.

Magu lawọn ọtẹlẹmuyẹ mu lọjọ Aje, Mọnde, to kọja, lori ẹsun ikowojẹ ti Minisita feti idajọ, Abubakar Malami, fi kan an.

Lati igba naa lo ti wa lahaamọ, bẹẹ lo n jẹjọ niwaju igbimọ iwadii kan ti ileeṣẹ Aarẹ ilẹ yii gbe kalẹ.

Leave a Reply