Jide Alabi
Nitori bi wọn ṣe doju kọ awọn agbebọn ti wọn fẹẹ pa a, ti wọn si doola ẹmi re, Gomina ipinlẹ Benue, Samuel Ortom, ti dupẹ lọwọ awọn ẹṣọ alaabo rẹ, bẹẹ lo si gboriyin fun wọn fun iṣẹ takuntakun ti wọn ṣe.
Gomina yii fi kun un pe ere maili kan ataabo loun sa lati bọ kuro lọwọ awọn Fulani darandaran to dena de mọto rẹ, ti wọn fẹẹ pa a ni ọjọ Abamẹta Satide, ọsẹ to kọja.
Ọrtom ni oun dupẹ gidigidi lọwọ awọn ẹṣọ alaabo ohun yii fun ipa ti wọn ko, o ni ọpẹlọpẹ wọn ti wọn le awọn agbebọn naa ti wọn ko fi le raaye pa oun. O ni bo tilẹ jẹ pe mẹfa pere ni awọn ẹṣọ laabo naa, sibẹ wọn ṣiṣẹ takuntakun lati gba ẹmi oun ninu ewu.
Bakan naa lo dupẹ lọwọ Ọlọrun fun okun ati agbara to fun un lati le sa ere ni iwọn kilomita kan ataabọ lai duro rara, o ni bi ki i baa ṣe pe ara oun duro giri ti oun le sa ere naa ni, ọtọ ni ohun ti iba ṣẹlẹ.
Ọkunrin naa ṣalaye pe mẹẹẹdogun ni awọn darandaran ti wọn di ihamọra yii ti wọn si bẹrẹ si i sa tẹle oun bi oun ṣe n sa lọ lai wọn bata. O ni afigba ti wọn le oun de eti odo kan bayii ki wọn too pada.
Gomina fi aidunnu rẹ han si igbesẹ naa, o ni ewu nla ni bi oun ko ba le lọ soko lai ko ẹsọ alaabo dani. O ni eyi fi ipo ti awọn wa nipinlẹ naa han.
Tẹ o ba gbagbe, ọjọ Abamẹta, Satide, ọsẹ to kọja ni wọn ni awọn Fulani darandaran ti wọn di ihamọra lọọ dena de ọkọ gomina naa, ti wọn si yọ si wọn lojiji ni Tyo Mu, loju ọna Gboko si Markurdi.
Markurdi la gbọ pe gomina naa n lọ nigba ti awọn agbebọn ti wọn pe ni Fulani darandaran bii mẹẹẹdogun yii yọ si wọn, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn lu mọto rẹ. Ọpẹlọpẹ awọn ẹṣọ alaabo to tẹle e ti wọn kọju ija si awọn eeyan naa ti wọn ko jẹ ki wọn ri gomina yii pa.
Ọpọlọpọ awọn eeyan, to fi mọ awọn gomina ni wọn ti bu ẹnu atẹ lu igbesẹ naa