Makinde ṣabẹwo si Oyetọla, o ni oun mọriri ipa to ko lori ọrọ LAUTECH

Florence Babaṣọla

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ṣeyi Makinde, ti ṣabẹwo si ojugba rẹ ni ipinlẹ Ọṣun, Alhaji Gboyega Oyetọla, lọọfiisi rẹ niluu Oṣogbo, o ni lati fi ẹmi imoore han lori bi ọrọ ituka ileewe Ladoke Akintola University of Technology (LAUTECH) ko ṣe mu wahala lọwọ loun ṣe wa.

Makinde, ẹni ti diẹ lara awọn kọmisanna rẹ ba lọ, sọ pe ipa manigbagbe ni Oyetọla ko lori ọrọ naa, o si ti han gbangba pe ẹni ti ko mọ ti ara rẹ nikan ni gomina naa i ṣe.

O sọ siwaju pe itan ko ni gbagbe Oyetọla pẹlu bo ṣe pa ifẹ ar ẹni ati ọrọ-oṣelu ti sẹgbẹẹ kan, to si fi anfaani silẹ lati jẹ ki ifẹ ọjọọwaju rere awọn akẹkọọ ileewe naa ṣe pataki si i.

O ni ni bayii ti ipinlẹ Ọṣun ti tuwọ lọrọ Lautech, iyẹn ko sọ pe ki idẹyẹsi wa rara, yala nileewosan tabi nileewe, o ni opin ti de ba nnkan ti wọn n pe ni ‘Osun Forum’ tabi ‘Oyo Forum’, gbogbo rẹ si ti di ‘Lautech Forum’ bayii.

Ninu ọrọ tirẹ, Gomina Oyetọla sọ pe bo tilẹ jẹ pe igbesẹ akin nigbesẹ ti oun gbe lori ọrọ Lautech, sibẹ adari rere ko gbọdọ jẹ ki ọrọ-oṣelu ba ọjọ-ọla awọn ọdọ ti wọn jẹ ogo orilẹ-ede jẹ.

O wa rọ Makinde lati tẹle gbogbo adehun ti ipinlẹ mejeeji ṣe ki wọn to pinya.

 

Leave a Reply