Ọlawale Ajao, Ibadan
Ijọba ipinlẹ Ọyọ, labẹ iṣakoso Gomina Ṣeyi Makinde, ti le awọn oṣiṣẹ mẹta danu lẹnu iṣẹ nileewe Oyo State Basic School, iyẹn ileewe awọn to ni ipenija oju to wa niluu Ogbomọṣọ, nipinlẹ Ọyọ.
Bakan naa nijọba fiya jẹ alakooso ati olukọ agba ileewe naa pẹlu bi wọn ṣe gbe wọn kuro nileewe ọhun lọ sile-ẹkọ mi-in to jinna rere.
Komiṣanna feto ẹkọ, imọ sayẹnsi ati imọ ẹrọ ninu ijọba naa, Ọgbẹni Rahman Abdul-Raheem, lo paṣẹ naa nitori iṣẹlẹ ibalopọ kan to waye nileewe ọhun ti wọn ti n ṣiṣẹ.
Laipẹ yii niroyin gba ori ẹrọ ayelujara nipa iṣẹlẹ ibalopọ lọna aitọ kan ti wọn lo waye laarin ọkan ninu awọn olukọ ileewe ọhun pẹlu akẹkọọ-obinrin kan nibẹ.
Ninu atẹjade ti kọmiṣanna feto ẹkọ fi ṣọwọ sakọroyin wa lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja lo ti kede ijiya awọn olukọ naa
Orukọ awọn olukọ ọhun, eyi ti ijọba gbe lọ sileewe mi-in nitori ki i ṣe awọn gan-an gan-an ni wọn huwa ibajẹ ọhun ni Abilekọ Adebiyi Rachael (olukọ agba) ati Abilekọ Akanbi Oluwaṣeun ti i ṣe alakooso ile-ẹkọ girama naa.
Ọgbẹni Abdul Raheem sọ ninu atẹjade rẹ ọhun pe lati origun mẹrẹẹrin ipinlẹ Ọyọ lawọn ti ri iwe ẹsun gba nipa aṣemaṣe to n waye laarin awọn oṣiṣẹ-kunrin atawọn akẹkọọ-binrin ileewe naa, ati pe igbimọ oluwadii ẹlẹni mẹrin ti ijọba gbe kalẹ lori iṣẹlẹ yii ti bẹrẹ iwadii to peye lori ọrọ naa.
O ni igbagbọ wa pe iwadii ati idajọ ododo ti ijọba pinnu lati ṣe lori ọrọ yii yoo da alaafia pada sileewe naa laipẹ jọjọ.