Makinde di gomina Ọyọ lẹẹkeji, ijọba ibilẹ mọkanlelọgbọn lo ti wọle

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ajọ eleto idibo ipinlẹ Ọyọ, labẹ isakoso Dokita Adeniran Tẹlla, ti kede Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, to n dije dupo gomina fun saa keji nipinlẹ naa gẹgẹ bii ẹni to jawe olubori ninu eto idibo gomina to waye nipinlẹ naa.

Ninu esi idibo ti wọn gbe jade lo ti fidi rẹ mulẹ pe ijọba ibilẹ mọkanlelọgbọn, ninu ẹtalelọgbọn to wa nipinlẹ naa ni Makinde ti gbẹyẹ lọwọ awọn ojugba rẹ, iyẹn Tẹslim Fọlarin, ti ẹgbẹ APC, ẹni to jawe olubori ni ijọba ibilẹ meji pere, nigba ti Adebayọ Adelabu, ti ẹgbẹ oṣelu Accord ko mu ijọba ibilẹ kankan.

Pẹlu esi idibo yii, Makinde ni yoo jẹ gomina keji ti yoo ṣe saa keji ninu itan ipinlẹ Ọyọ lẹyin Oloogbe Ajimọbi ti wọn dibo yan sipo gomina lẹẹkeji nigba to wa laye.

Awọn ijọba ibilẹ ti Makinde ti jawe olubori ni Ọna Ara, Ariwa Iwọ Ooorun Ibadan, Ila Oorun Ibarapa, Ijọba ibilẹ Afijio, Atiba, Oriire, Guusu Iwọ Oorun Ibadan, Oluyọle, Atisbo, Ila Oorun Saki, Surulere, Itẹsiwaju, Ogo Oluwa, Ọlọrunṣogo, Ariwa Ila Oorun Ibadan, Guusu Ogbomọsọ,  Guusu Ila Oorun Ibadan, Ariwa Ibarapa, Aarin Gbungbun Ibarapa, Ariwa Ogbomọsọ, Ẹgbẹda, Ariwa Ibadan, Isẹyin, Guusu Saki, Iwajọwa, Lagelu, Kajọla, Ido, Iwọ Oorun Ọyọ ati Akinyẹle.

Ijọba ibilẹ meji, Irepọdun ati Itesiwaju.

Adebayọ Adelabu ko mu ijọba ibilẹ kankan

Leave a Reply