Ọlawale Ajao, Ibadan
Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinia Ṣeyi Makinde, ti pinnu lati ṣepade pẹlu awọn tọọgi at’awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun kaakiri igboro Ibadan.
Kọmiṣanna feto iroyin, aṣa ati irinajo afẹ nipinlẹ Ọyọ, Ọmọwe Wasiu Ọlatubọsun, lo sọrọ yii lẹyin ipade to ṣe pẹlu awọn ileeṣẹ eleto aabo bii Amọtẹkun, Fijilante, OPC, atawọn Agbẹkọya, n’Ibadan, l’Ọjọbọ, Tọsidee ọsẹ yii.
Erongba ijọba pẹlu ipade ọhun gẹgẹ bi Ọmọwe Ọlatubọsun ṣe sọ ni lati le bori ipenija eto aabo nigboro Ibadan ati kaakiri ipinlẹ Ọyọ.
Komiṣanna yii gba pe bi ijọba ba le fikun lukun pẹlu awọn ọmọ aye kaakakiri, itajẹ-eeyan-silẹ to maa n waye latari ija igboro laarin awọn tọọgi ati laarin awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun yoo dopin.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, “A gbe ọrọ awọn tọọgi pẹlu awọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, eyi to maa n la ofo ẹmi ati dukia lọ lọpọ igba yẹwo ninu ipade igbimọ awọn alaṣẹ ijọba. A si ti pinnu lati ṣepade pẹlu wọn.
“Ijọba Gomina Ṣeyi Makinde ti ṣetan bayii lati lọọ maa ba awọn ọmọ igboro atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun wọnyi nibuba wọn fun ifikunlukun lati fopin si ija ajaku-akata ti wọn maa n bara wọn ja.”
Njẹ bawo ni Makinde atawọn igbimọ ijọba rẹ yoo ṣe mọ ibuba awọn ọmọ igboro atawọn ọmọ ẹgbẹ okunkun, Ọmọwe Ọlatubọsun sọ pe niwọn igba tawọn eeyan naa ki i ṣe ajeji sawọn agbofinro, awọn ikọ eleto aabo bii Amọtẹkun, Fijilante ati bẹẹ bẹẹ lọ ni yoo mu awọn lọ sibuba awọn ẹruuku naa.
Nigba to n rọ awọn ọmọ iṣọta lati gba alaafia laaye ki wọn yee ja ija aja-fẹmi-ṣofo mọ, kọmiṣanna yii sọ pe lẹyin ti ijọba ba ti ṣepade pẹlu wọn tan, bi ọwọ ba tẹ ẹnikẹni ninu wọn nidii ija igboro, ohun ti ijọba yoo foju iru ẹni bẹẹ ri ko ni i ṣee fẹnu lasan royin.