Ọlawale Ajao, Ibadan
Orin iyin lawọn Musulumi kaakiri ipinlẹ Ọyọ n kọ ki gomina ipinlẹ naa, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, bayii pẹlu bo ṣe fi ọkọ bọọsi tuntun kan ta ijọ awọn Musulumi moṣalaaṣi nla ilu Ibadan lọrẹ.
Lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja, ni gomina naa fi kọkọrọ mọto ọhun le wọn lọwọ ninbu ọgba mọṣalaaṣi ọhun to wa l’Ọjaba, nigboro Ibadan.
Nigba to n ṣalaye ohun to ṣokunfa ẹbun pataki naa, Oludamọran Makinde lori ọrọ ẹsin, Alhaji Abdul-Rasheed, to ṣoju fun un nibi eto naa sọ pe igbesẹ yii jẹ ara imuṣẹ awọn ileri ti Makinde ṣe lasiko ipolongo idibo rẹ pe ijọba oun maa ṣatilẹyin fun araalu ninu ohun gbogbo ti wọn ba n ṣe lai ya ẹṣin kan sọtọ.
O ni oun mọ pe ọkọ ti oun fun awọn jànmón-ọ̀n mọṣalaaṣi Ọja’ba yii yoo ṣeranlọwọ daadaa nipa ihinrere ẹṣin Islam.
Makinde fi kun un pe iṣọkan laarin awọn ẹlẹsin lo daa lati maa wa, nitori idagbasoke ko le tete ba awujọ yoowu ti ko ba pataki irẹpọ laarin awọn eeyan rẹ.
Nigba to n fi ẹmi imoore han si oore gomina yii, Imaamu agba ilẹ Ibadan, Sheik Abdul-Ganiyy Abubakr Agbọ́tọmọkékeré ṣapejuwe Makinde gẹgẹ bii ẹni to mọ riri adua ti awọn Musulumi ipinlẹ Ọyọ n ṣe fun un.
Oun naa waa rọ gbogbo olujọsin lati maa lepa alaafia lawujọ lai fi ti ẹsìn ṣe.
Ni pataki ju lọ, o ni awọn lèmọ́ọ̀mù atawọn ààfáà ni ipa pataki lati ko lati ri i pe awọn eeyan n gbe igbe aye alaafia ati iṣọkan lawujọ.