Ọlawale Ajao, Ibadan
Ni nnkan bii aago mejila ku iṣẹju diẹ ni oludije funpo aarẹ lorukọ ẹgbẹ PDP, Alaaji Atiku Abubakar, ati igbakeji rẹ, Ifeanyi Okowa, awọn igbimọ amuṣẹṣe ẹgbẹ naa atawọn lookọlookọ ẹgbẹ ọhun mi-in balẹ sile ijọba ipinlẹ Ọyọ to wa ni Agodi, niluu Ibadan, nibi ti Gomina Ṣeyi Makinde ti gba wọn lalejo.
Bi wọn ṣe de naa ni Atiku ati awọn ti wọn kọwọọrin pẹlu rẹ bii awọn ọmọ igbimọ amuṣẹṣe, Gomina ipinlẹ Sokoto, Aminu Tambuwal, Oluṣẹgun Mimiko, Jumọkẹ Akinjide, Dino Melaye, Gomina ipinlẹ Ọṣun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Ademọla Adeleke atawọn mi-in wọle ipade bonkelẹ ti ko ju isẹju mẹẹẹdogun lọ.
Lara awọn ti wọn tun wa pẹlu rẹ ninu ipade yii ni oludije funpo gomina nipinlẹ Ogun, Ladi Adebutu, Babangida Aliyu Muazu, Alagba Wọle Oyelẹsẹ, oludjie funpo gomina nipinlẹ Ekiti, Eyitayọ Jẹgẹdẹ, Peter Ayọdele Fayoṣe ti i ṣe gomina ipinlẹ Ekiti tẹlẹ.
Lẹyin eyi ni gbogbo wọn kọwọọrin lọ si Gbongan Theophilus Ogunlesi to wa ni adojukọ ọsibitu UCH, niluu Ibadan, nibi ti Atiku ti ba awọn aṣoju ẹgbẹ naa sọrọ.
Lasiko ipade naa ni Gomina Ṣeyi Makinde sọ pe to ba jẹ pe loootọ ni wọn fẹ ki iṣọkan wa ninu ẹgbẹ naa, ti wọn si fẹẹ tẹle ilana pin-in-re, la-a-re, afi ki alaga ẹgbẹ naa, Iyorchia Ayu fipo alaga to wa naa silẹ.
Makinde ni ohun ti awọn ọmọ ẹgbẹ PDP nilẹ Yoruba duro fun ni pe bi wọn yoo ba mu isọkan wa ninu ẹgbẹ naa, o gbọdọ han ninu awọn ti wọn ko sipo oloye ẹgbẹ.
O waa rọ Atiku lati pẹtu si alaga ẹgbẹ naa bayii ninu pe ko fi ipo naa silẹ ki oludije lati iha Guusu le bọ si. O ni ohun ti oun atawọn gomina ẹlẹgbẹ oun kan ti n pariwo rẹ niyi, niori igbesẹ yii nikan lo le mu iṣọkan ti wọn n pariwo wa, ti yoo si fi ẹgbẹ naa han bii eyi ti awọn aṣaaju wọn ko fi si agbegbe kan ju ekeji lọ.