Awọn adigunjale ya bo ile-ijọsin n’llọrin, wọn ji ọpọlọpọ dukia pasitọ lọ

 

Ibrahim Alagunmu, Ilọrin

L’Ọjọ Aje, Mọnde, ọsẹ yii, ni awọn afurasi adigunjale kan ya bo ile pasitọ ile-ijọsin Saint Barnabas Cathedral, Anglican, to wa ni agbegbe Sabo Oke, niluu Ilọrin, nipinlẹ Kwara, ti wọn si ji awọn dukia ọkẹ aimọye miliọnu Naira lọ.

ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii aago meji aabọ oru ọjọ Aje ni awọn afurasi adigunjale naa gun alupupu wọ agbegbe naa, wọn kọkọ ja geeti abawọle, ti wọn si tun ja ilẹkun meji ki wọn too gun oke alajakeji lọọ ba pasitọ ati mọlẹbi rẹ.

Pasitọ Reverend Isaiah Ibikunle Afọlayan, ti wọn kọ lu ile rẹ ọhun sọ pe lasiko ti awọn n sun lọwọ laago meji aabọ oru ni awọn sadeede ri ọkan lara awọn adigunjale naa to wọ yara pẹlu ohun ija oloro, to si sọ pe ti awọn ba pariwo, iku ni. O paṣẹ pe ki awọn doju bolẹ. Pasitọ ni oun beere lọwọ rẹ pe ta ni ọ? Kin ni o n ṣe nibi? Lo ba gbe ẹrọ alagbeelean oun, o si jade.  Ọpọlọpọ awọn dukia olowo iyebiye bii ẹrọ alagbeeletan towo rẹ  to miliọnu kan le lọọọdunrun Naira (N1.3 million), Amohunmaworan (TV) ati ẹrọ ibanisọrọ rẹ ni wọn ji ko.

Afọlayan sọ pe ki i ṣe eeyan kan lo ṣoṣo lo wa, ṣugbọn ẹnikan ṣoṣo lo wọnu yara pẹlu ohun ija oloro. O ni awọn ti fi iṣẹlẹ naa to ileesẹ ọlọpaa leti.

Pasitọ Taiwo Ajibọla lati agbegbe Sabo-Oke, to ba awọn oniroyin sọrọ sọ pe awọn ọdẹ adugbo ri awọn adigunjale naa ti wọn gbe alupupu wa, ti awọn ọdẹ tan ina si wọn, ki wọn too sa lọ.

Tẹ o ba gbagbe, awọn olugbe Sabo-Oke Ilupeju, nijọba ibilẹ Ila Oorun ( Ilọrin East), ipinlẹ Kwara, ni wọn ti n pe fun idasilẹ ẹka ajọ ẹṣọ alaabo sifu difẹnsi lagbegbe naa lati mu ki eto aabo gbopọn nitori aisi eto aabo to n ba awọn eeyan agbegbe naa finra.

Leave a Reply