Ipo Alaafin da wahala silẹ laarin awọn ọmọọba

Ọlawale Ajao, Ibadan

Pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, afaimọ ni eto lati yan Alaafin Ọyọ tuntun ko ni i fori ṣanpọn. Idi ni pe pupọ ninu awọn idile to n dupo ọba naa ni wọn ti sọ pe ki awọn afọbajẹ da eto naa duro.

Mẹsan-an ninu idile mọkanla to n dupo Alaafin ni wọn panu-pọ sọrọ naa ninu ipade ti wọn ṣe pẹlu awọn oniroyin niluu Ọyọ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii.

Orukọ awọn idile mẹsẹẹsan ọhun ni Adelabu, Adediran Ẹsẹ Apata, Ọlanitẹ, Adeṣiyan, Adeṣọkan Baba Idọdẹ, Itẹade Abidẹkun, Adeitan, Tẹlla Okitipapa ati Tẹlla Agbojulogun.

Nigba to n sọrọ lorukọ awọn idile mẹsẹẹsan-an, Ọmọọba Afọlabi Adeṣina (lati idile Adeitan) fi aidunnu wọn han si igbesẹ ti ijọba ipinlẹ Ọyọ n gbe lori ọrọ eto lati fi ọba tuntun jẹ lode Ọyọ.

Gẹgẹ bo ṣe sọ, “Ninu lẹta ti ijọba kọ si awọn afọbajẹ lọjọ kẹsan-an, oṣu Kẹjọ, ọdun yii (2022), ni wọn ti sọ pe ọkan ninu awọn ọmọ oye to jẹ ọmọ idile Agunloye ni ki awọn Ọyọmesi (afọbajẹ) fi jọba.

“Eyi fi han pe ijọba n ṣe ojuṣaaju, wọn n gbe lẹyin idile Agunloye nikan, nigba to jẹ pe idile mẹwaa lo yẹ ki wọn fun lanfaani lati dupo ọba.

“O yẹ ki ijọba ni suuru ki awọn ẹjọ to wa ni kootu lori ọrọ oye yii pari tan ki wọn too ṣeto lati fi ọba tuntun jẹ”.

Awọn idile mẹsẹẹsan-an yii waa rọ awọn Ọyọmesi, ti wọn jẹ afọbajẹ Ọyọ lati da eto ifọrọwerọ ti wọn n ṣe lọwọ fun awọn ọmọ oye mẹrẹẹrindinlaaadọrun-un (86) ti wọn jẹ kikida idile Agunloye duro titi ti gbogbo wahala to wa nilẹ yii yoo fi yanju.

Leave a Reply