Akẹkọọ mẹfa la ti ni ki wọn lọọ rọọkun nile lori ẹsun iwa ibajẹ – Ọga Fasiti Ọṣun

Florence Babaṣọla, Oṣogbo

Ọga agba Fasiti Ọṣun, Osun State University, Ọjọgbọn Ọdunayọ Clement Adebọoye, ti sọ pe gbogbo igba lawọn alakooso ileewe naa n ṣe ilanilọyẹ fawọn akẹkọọ lori pataki gbigbe igbe aye ọmọluabi, bẹẹ ni awọn ko fi ọwọ pa eyikeyii to ba huwa ti ko bojumu lara wọn lori rara.

Adebọoye ṣalaye pe akẹkọọ mẹfa lawọn ti paṣẹ pe ki wọn lọọ rọọkun nile ni ẹka fasiti naa to wa niluu Ikire, ko baa le jẹ ẹkọ fawọn akẹkọọ to ku.

Lasiko to n yannana oniruuru eto ti wọn ti la kalẹ fun ayẹyẹ ikẹkọọ-jade ẹlẹẹkọkanla iru ẹ (11th Convocation) ni Ọjọgbọn Adebọoye ṣalaye pe akẹkọọ ẹgbẹrun meji o le mẹtalelọgbọn (2033) ni wọn yoo kẹkọọ-jade ni Fasiti Ọṣun.

Ninu wọn, awọn marunlelogoji ni wọn pari pẹlu First Class Honours, awọn to le ni ẹẹdẹgbẹta ni wọn pari pẹlu Second Class (Upper), awọn ẹgbẹrun kan ati mejila ni wọn pari pẹlu Second Class (Lower), nigba ti akẹkọọ kan ṣoṣo pari pẹlu Paasi lẹyin to ti lo ọpọ ọdun nileewe naa.

O ṣalaye pe awọn eeyan meji ti wọn ti laamilaaka lẹnu iṣẹ ti wọn yan laayo ni wọn yoo fi oye da lọla lasiko ayẹyẹ naa, awọn naa si ni Dokita Lawrence Sẹgun Aina to jẹ alaga Oodua Group of Companies nigba kan ati Dokita (Arabinrin) Victoria Adunọla Samson to jẹ oludasilẹ ileepo BOVAS.

O fi kun ọrọ rẹ pe fun igba akọkọ, eto kan yoo wa lasiko ayẹyẹ  ti yoo waye laarin ọjọ kọkanla, oṣu Kẹsan-an, titi di ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kẹsan-an ọhun, eleyii ti wọn pe ni ‘Meet the Vice-Chancellor’ fun awọn akẹkọọ ti wọn yege ju lọ (First Class Awardees).

 

Adebọoye sọ pe lara awọn aṣeyọri fasiti naa ti inu oun dun ju lọ le lori ni bi iyipada ṣe ba iwa awọn akẹkọọ nipasẹ idanilẹkọọ oorekoore tawọn n ṣe fun wọn lori ewu to wa nidii lilo oogun oloro, ifipabanilopọ, magomago lasiko idanwo ati didarapọ mọ ẹgbẹ okunkun.

 

Yatọ si ẹkọ iwe, Giwa yii sọ pe oniruuru iṣẹ ọwọ lawọn akẹkọọ ti wọn fẹẹ ṣayẹyẹ ikẹkọọ-jade naa lanfaani si lasiko ti wọn lo nibẹ, pupọ awọn iṣẹ ọwọ naa lawọn yoo ṣafihan wọn lasiko ayẹyẹ naa.

Leave a Reply