Makinde gbẹsẹ lori ofin konilegbele aago mẹwaa alẹ l’Ọyọọ

Lẹyin agbeyẹwo loriṣiiriṣii, ijọba ipinlẹ Eko ti fopin si isede konilegbele aago mẹwaa alẹ to ti wa nipinlẹ naa lati bii oṣu diẹ sẹyin nitori arun Koronafairọọsi to gbode.

Gomina ipinlẹ naa, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde, lo sọ ọrọ yii di mimọ nipasẹ Akọwe Iroyin rẹ, Ọgbẹni Taiwo Adisa.

Ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ yii ni Adisa fi ikede naa sita, nibi to ti sọ pe ijọba ti fopin si konilegbele alaago mẹsan-an naa lẹyin ayẹwo ati akiyesi loriṣiiriṣii.

Ijọba waa rọ awọn araalu lati maa pa gbogbo ofin to rọ mọ arun Korona mọ. Wọn ni nitori pe ijọba fagi le aṣẹ konilegbele yii ko tumọ si pe ko si Korona niluu mọ, awọn araalu ni ki wọn maa fẹṣọ ṣe, ki wọn si pa ofin imọtoto mọ.

Leave a Reply