Faith Adebọla, Eko
Ẹgbẹ oṣelu All Progressive Congress (APC) tipinlẹ Eko ti ṣeto idibo abẹle lati yan ẹni ti yoo dije lorukọ ẹgbẹ naa ninu eto idibo sipo Sẹnetọ fun ẹkun idibo Ila-Oorun Eko ti yoo waye ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kẹwaa, ọdun yii, Ọgbẹni Tokunbọ Abiru ni ẹgbẹ naa fa kalẹ, oun lo jawe olubori ninu eto idibo abẹle ọhun.
Ọjọruu, Tọsidee, ọsẹ yii, leto idibo abẹle naa waye ninu ọgba ijọba ibilẹ Ṣomolu, ilana gbangba-laṣa-a-ta si ni wọn lo.
Ọnarebu Godbless Diriaari to wa lati Abuja lẹgbẹ fun laṣẹ lati ṣe alaga igbimọ eleto idibo ẹgbẹ fun ti yiyan ọmọ oye ọhun, lo kede pe aropọ ibo ti iye rẹ jẹ ẹgbẹrun mẹrin, okoolelẹgbẹrin o din mẹta (4,837) ni wọn di fun Abiru, o ni ko si oludije mi-in to ba a du ipo ọhun, bẹẹ ni ko si ibo akadanu rara, wọọrọwọ si leto ọhun lọ lai si wahala kankan.
Latari eyi, Diriaari kede pe Tokunbọ Abiru lo yawe olubori ninu eto idibo abẹle naa, oun si ni yoo dije labẹ asia ẹgbẹ APC fun ipo Sẹnetọ to ṣi silẹ ọhun.
Ṣaaju, awọn meje ni wọn ti kọkọ fi ifẹ ọkan han lati kopa ninu eto idibo abẹle naa, ti Tokunbọ si jẹ ọkan lara wọn. Awọn mẹfa to ku ni Ọgbẹni Ṣẹgun Ogunlewe to ti figba kan jẹ olori awọn oṣiṣẹ ọba ipinlẹ Eko, Ọgbẹni Rotimi Ogunlẹyẹ, kọmiṣanna fun eto sọgbẹ digboro tẹlẹ ri, ati Ọgbẹni Lekan Ogunbanwo, ọga agba ileeṣẹ tẹlifiṣan Eko, LTV, nigba kan.
Awọn mẹta to ku ni aṣofin ipinlẹ Eko tẹlẹ, Ọgbẹni Ọlanrewaju Ọdẹsanya, alaga ẹgbẹ Ikorodu-Ọga, Ọgbẹni Oluwaṣẹgun Abiru, ati igbakeji alagba ẹgbẹ APC l’Ekoo, Oloye Kaoli Olusanya.
Ṣugbọn bo ṣe ku wakati perete ki eto idibo abẹle naa bẹrẹ ni ipade kan waye laarin awọn oludije naa ati awọn aṣofin Eko, ti olori wọn, Mudashiru Ọbasa, ṣaaju wọn. Lẹyin ipade ọhun lawọn oludije mẹwẹẹwa yooku kede pe awọn ko dije mọ, Tokunbọ Abiru lawọn maa tẹle, oun ni kawọn alatilẹyin awọn dibo fun, bẹẹ naa ni Ọbasa sọ pe ẹyin Tokunbọ ni awọn aṣofin Eko duro si digbi. Eyi lo fa a to fi jẹ gbogbo ibo ti wọn ka pata ni wọn ka fun un.
Ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kẹta, ọdun 1964, ni wọn bi Tokunbọ Abiru, ọdun yii lo dẹni ọdun mẹrindinlọgọta. O lọ si Fasiti ipinlẹ Eko, LASU, o si gboye ninu imọ ọrọ-aje (Economics) ko too di ọmọ ẹgbẹ awọn oluṣiro owo ilẹ wa, ICAN. Oun ni kọmiṣanna feto inawo ipinlẹ Eko lasiko ti Babatunde Faṣhọla fi jẹ gomina, o ti figba kan wa lara awọn ọga agba ileefowopamọ First Bank, ko to o bọ sipo ọga agba ileefowopamọ Polaris Bank, ipo ọhun lo si wa titi di ọjọ kẹrinlelogun, oṣu kẹjọ, to kọja yii, nigba to kọwe fipo silẹ lati le dije fun aaye Sẹnetọ to ṣi silẹ ọhun.
Tẹ o ba gbagbe, Oloogbe Bayọ Ọshinọwọ ti inagijẹ rẹ n jẹ Pẹpẹrito lo wa nipo naa ki iku too yọwọ rẹ lawo lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹfa, ọdun yii, latari bo ṣe lugbadi arun aṣekupani Koronafairọọsi.