Makinde ti ọgọrin ileeṣẹ pa nipinlẹ Ọyọ

Ileetura, ṣọọbu atawọn ileetaja igbalode to le lọgọrin  nijọba ti pa nipinlẹ Ọyọ. Premier Hotel, to wa ni Mọkọla, n’Ibadan, iyẹn ileetura to jẹ ajumọni awọn ijọba ipinlẹ ilẹ Yoruba wa lara awọn ibi ti Makinde ti pa.

Lara awọn tijọba tun ti pa ni gbọngan igbalejo nla kan to gbajugbaja laduugbo Ẹlẹyẹle, n’Ibadan, pẹlu ile itaja bii ọgọrin mi-in.

Komiṣanna feto ayika ati ohun alumọọni nipinlẹ Ọyọ, Ọgbẹni Abiọdun Oni, lo ṣaaju ikọ eleto ilera rin awọn irinajo ọhun kaakiri ilu Ibadan.

Adugbo Mọkọla, Sango ati Ẹlẹyele lawọn ileetura atawọn ileetaja ti wọn ti pa ọhun pọ si ju lọ.

Lara awọn ti wọn kọwọọrin pẹlu komiṣana ni Oludari ẹka eto ilera, Ọgbẹni Rogba Adedigba, Alaamojuto ileeṣẹ imọtoto ayika, awọn oṣiṣẹ ẹka imọtoto ayika atawọn agbofinro bii Amọtẹkun, Operation Burst ati bẹẹ bee lọ.

Nigba to n bawọn oniroyin sọrọ lẹyin ti wọn pari iṣẹ ọhun tan, kọmiṣanna yii sọ pe, “a ni lati ti awọn ile wọnyi pa nitori pe ọpọ igba la ti kilọ fun wọn, ṣugbọn ti wọn kọ lati ṣe ohun to yẹ ki wọn ṣe. A tun fun wọn ni gbedeke ọjọ meje, ṣugbọn ibi pẹlẹbẹ lọbẹ fi lelẹ.

“O jẹ ẹdun ọkan fun mi pe gbogbo ba a ṣe n ṣakitiyan lati le jẹ ki ayika wa wa ni imọtoto, niṣe lawọn kọlọransi kan n fa aago ilọsiwajurẹ sẹyin nipa bi wọn ṣe n kọti ikun si ofin ati gbogbo ikilọ nipa eto imọtoto.”

Lẹyin eyi ni kọmiṣana atawọn ikọ rẹ tẹsiwaju lọọ ṣe Idanilẹkọọ fawọn ontaja lọja Gbaremu ati ileetaja Adelabu, to wa laduugbo Challenge, n’Ibadan, lori pataki eto imọtoto ayika ati ọna ti wọn le gba maa tọju ayika wọn.

 

Leave a Reply