Makinde yọ ọga agba Fasiti LAUTECH nipo

Ọlawale Ajao, Ibadan

Gomina ipinlẹ Ọyọ, Ẹnjinnia Ṣeyi Makinde ti yọ Ọjọgbọn Michael Olufisayọ Ologunde kuro nipo gẹgẹ bii ọga agba Fasiti imọ ẹrọ ipinlẹ Ọyọ ta a mọ si Ladoke Akintola University of Technology (LAUTECH), to wa niluu Ogbomọṣọ.

Ninu atẹjade ti Ọjọgbọn Ọlasunkanmi Ọlalẹyẹ ti i ṣe kọmisanna feto ẹkọ ni ipinlẹ Ọyọ fi ṣọwọ sawọn oniroyin nirọlẹ ọjọ Ẹti, Furaidee, opin ọsẹ yii, lo ti sọ pe ki ọkunrin naa fa eto akoso ileewe giga naa le ẹni to ba kangun si i nipo lọwọ.

Loju ẹsẹ ni wọn ni ki adele ọga tuntun naa maa tẹsiwaju ninu eto iṣakoso LAUTECH,  nitori wọn ko fẹ ki irọloye Ọjọgbọn Ologunde ṣakoba fun eto ẹkọ ati eto iṣakoso ileewe naa.

Ni nnkan bii ọsẹ meloo kan sẹyin ni Gomina Makinde fẹsun kan ọga agba LAUTECH ti wọn rọ loye yii pe ọkunrin naa lo wa nidii ija ti awọn oṣiṣẹ ileewe naa ja laipẹ yii, pe dandan ni ki ijọba ṣafikun owo-oṣu awọn.

Gomina ṣalaye pe nigba ti awọn oṣiṣẹ LAUTECH bẹrẹ ija fun ẹkunwo yii, oun gbe igbimọ oluwadii kan dide lati mọ idi ti wọn ṣe faake kọri pe awọn ko fara mọ iye ti ijọba n fun wọn gẹgẹ bii owo-oṣu mọ, ṣugbọn si iyalẹnu oun, awọn oluwadii ọhun jabọ pe ọga agba Fasiti naa lo kọ awọn oṣiṣẹ wọnyi lati ja  fun ẹkunwo, o ni ohun to ba fi le mu ki ijọba ipinlẹ Ọyọ san biliọnu mẹjọ naira fun ipinlẹ Ọṣun fun yiyọ ti wọn yọwọ kuro ninu awọn to ni ileewe naa, o yẹ ki wọn le ṣafikun owo-oṣu awọn naa.

O ṣee ṣe ko jẹ nitori ọrọ yii ni gomina naa ṣe binu yọ ọjọgbọn yii nipo iṣakoso LAUTECH, to si fi ẹlomi-in rọpo rẹ lọgan.

 

Leave a Reply