Maliki tun lọọ jale lẹyin to tẹwọn de ni Ṣaki

Olu-Theo Omolohun,  Oke-Ogun

Ogbologboo afurasi ọdaran kan, Kazeem Maliki, ẹni ọdun mẹtadinlogoji lọwọ ọlọpaa ti tẹ, to si ti n jẹjọ nile-ẹjọ Majisreeti kin-in-in to wa laduugbo Idi Araba, niluu Ṣaki, nipinlẹ Ọyọ, latari ẹsun ole jija ti wọn fi kan an, bẹẹ o ṣẹṣẹ de lati ẹwọn lori ẹsun ole jija ni.

Ọjọbọ, Tọsidee, ọsẹ to kọja yii, ni igbẹjọ bẹrẹ ni kootu ọhun, ibẹ lọkunrin naa ti jẹwọ pe ọmọ bibi ilu Agọ-Arẹ loun, iṣẹ awakọ loun si n ṣe.

Nigba ti Agbefọba, Inspẹkitọ AbdulMumuni Jimba, n ka ẹsun mẹta ti wọn fi kan an si i leti, o ṣalaye pe ni deede aago mẹfa aabọ aṣaalẹ ogunjọ, oṣu kẹwaa, ọdun yii, ni wọn ka afurasi yii mọ yara oniyara to wa ni agboole Baba Oge, laduugbo Iya, niluu Ṣaki, nibi to ti n ji aṣọ alaṣọ ko pẹlu awọn nnkan ẹṣọ oriṣiiriṣii.

Aropọ owo ẹru ti wọn ka mọ ọn lọwọ jẹ ẹgbẹrun lọna ojilelaaadọrin naira. Matthew Ojo ni wọn lo ni awọn dukia ọhun. Ẹsun keji ati ikẹta ni wiwọ ile onile lọna aitọ ati ole jija.

Maliki ko tiẹ fakoko ṣofo nigba ti won bi i boya o jẹbi tabi ko jẹbi, loju ẹsẹ lo ti gba pe oun jẹbi ẹsun mẹtẹẹta.

Adajọ I. O. Uthman waa bi i leere boya igba kan wa to ti wa sile-ẹjọ naa ri fun ẹsun iwa ọdaran, tori oju rẹ jọ ẹni toun mọ. Asiko yii ni agbefọba salaye pe olujẹjọ ti maa n paara awọn ile-ẹjọ agbegbe ọhun, latori ẹsun kan si omi-in. O ni ẹẹkẹta ree ti afurasi ọdaran naa yoo gba idajọ lori ẹsun ole jija yii kan naa.

O tẹ siwaju pe olujẹjọ yii wa lara awọn ti Adajọ agba ipinlẹ Ọyọ, Munta Abimbọla, foju aanu wo lọdun 2019, lakooko ti wọn ṣabẹwo sawọn ọgba ẹwọn kaakiri ipinlẹ Ọyọ. Inspẹkitọ Jimba ran adajọ leti pe lọdun 2020 kan naa ta a wa ninu rẹ yii, afurasi ọdaran naa ti gba idajọ ẹwọn oṣu mẹta lori ẹsun ole jija, abọde ẹwọn ọhun lo tun lọọ fọle onile tọwọ tun fi ba a yii.

Jimba waa ni kile-ẹjọ fun oun laaye lati le ṣa awọn ẹsun ọdaran naa papọ, kile-ẹjọ le mọ ijiya to tọ lati fun un, tori iwa ọkunrin yii ti fihan pe o ti jingiri ninu ole jija.

Ẹbẹ agbefọba yii lo mu ki adajọ paṣẹ pe ki wọn ṣi fi afurasi naa sahaamọ awọn ọlọpaa titi ọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu kọkanla yii, ti igbẹjọ yoo maa tẹ siwaju.

 

Leave a Reply