Mama Rainbow dẹni ọgọrin ọdun laye

Faith Adebọla

Manigbagbe ni ọjọ kẹrindinlogun, oṣu Kẹwaa, ọdun 2022,  jẹ nigbesi aye ọkan lara opomulero iṣẹ tiata lorileede yii, paapaa nidii ere Yoruba, Abilekọ Idowu Philips, tawọn eeyan mọ si Mama Rainbow, tori ọjọ naa lọjọọbi rẹ, ọjọ yii lo dẹni ọgọrin (80) ọdun laye.

Pẹlu idunnu nla lawọn eeyan fi n rọ lọ sile mama agbalagba yii lọjọ naa, ọpọ awọn olulufẹ wọn, mọlẹbi ati awọn aladuugbo ni wọn ko lọ sileejọsin wọn lọjọ naa, tori ọjọ Aiku, Sannde, lọjọ to bọ si, ọdọ Mama Rainbow ni wọn ti lọọ ṣe isin.

Isin idupẹ akanṣe kan ni wọn ṣeto fun mama naa ni ṣọọṣi to ti n ṣe oludari ijọ, iyẹn ṣọọṣi Kerubu ati Serafu kan to wa lagbegbe Ojodu, l’Ekoo.

Mama naa fọpẹ f’Ọlọrun bawọn eeyan ṣe n rọjọ adura fun un, pẹlu orin ọpẹ ọlọkan-o-jọkan to waye.

Lẹyin eyi lo ṣe itọrẹ aanu fawọn alaini, wọn fi ọpọlọpọ ẹbun oniruuru tọrẹ.

A gbọ pe eto n lọ lọwọ lati ṣayẹyẹ ọjọọbi to larinrin fun eekan oṣere yii lọjọ Tọsidee to n bọ.

Lori ikanni Instagiraamu ati fesibuuku rẹ, niṣe lawọn ololufẹ Iya Rainbow n kan saara si i fun iṣẹ taakun-taakun to ti ṣe lagbo tiata, ati bo ṣe n lo iyoku igbesi-aye ẹ lati ṣiṣẹ Oluwa. Aka-i-ka-tan awọn onitiata bii Ọga Bello, Jide Kosọkọ, Fathia Balogun, Fausat Balogun ti wọn n pe ni Madam Sajẹ, Iya Ereko, Saheed Balogun, Kẹmi Korede, Mistura Asunramu, Adunni Ade, Binta Ayọ Mọgaji, Yọmi Fabiyi, Ronkẹ Oṣodi Oke, Peju Ogunmọla, Aluwẹ, Yọmi Fash-Lanṣo, Ibrahim Chatta, Kunle Afod, Folukẹ Daramọla, Yinka Quadri, Ogogo, Lọla Idijẹẹ, Fali Werepe, Iyabọ Ojo, Bimpe Akintunde, Dele Odule ati bẹẹ bẹẹ lọ, awọn olorin bii Saheed Osupa Akorede, Alabi Pasuma, Shanko Raheed, Sulaiman Adekunle, Shefiu Alao, atawọn oloṣelu kan fi atẹjiṣẹ to n wuni lori ṣọwọ si obinrin akọni lori itage yii.

Leave a Reply