Faith Adebọla
Ṣe ẹ ranti gbajugbaja oloṣelu obinrin ọmọ bibi ipinlẹ Taraba nni, Aisha Jummai Alhassan, ti inagijẹ rẹ n jẹ ‘Mama Taraba,’ minisita tẹlẹ naa ti jade laye lẹni ọdun mọkanlelọgọta.
Amugbalẹgbẹẹ feto iroyin rẹ, Ọgbẹni Suleiman Dantsoho, lo fidi iku mama na mulẹ ninu atẹjade kan. O ni ileewosan kan ilu Cairo, lorileede Egypt, ni mama naa ku si lọsan-an ọjọ Ẹti, Furaidee yii.
Tẹ o ba gbagbe, Mama Taraba ni Aarẹ Muhammadu Buhari yan sipo minisita fun ọrọ awọn obinrin ati nnkan amayedẹrun (Women Affairs and Social Development) lọdun 2015, lẹyin to ti dije fun ipo gomina ipinlẹ Taraba labẹ asia ẹgbẹ oṣelu APC, ṣugbọn to fidi rẹmi, Darius Ishaku lo jawe olubori lorukọ ẹgbẹ oṣelu PDP.
Ọjọ ketadinlọgbọn, oṣu keje, ọdun 2018, lo kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii minisita, nigba ti wọn igbimọ to n yẹ awọn ondije fun ipo gomina labẹ ẹgbẹ oṣelu APC yọ orukọ rẹ kuro lara awọn ti wọn maa kopa ninu idibo abẹle, eyi ni ko si jẹ ko le kopa ninu eto idibo sipo gomina lọdun 2019.
Atẹjade naa sọ pe eto ti n lọ lati gbe oku rẹ wale, ki wọn si sin in bo ṣe yẹ.