Adewumi Adegoke
Gbogbo awọn ololufẹ ọga awọn onimọto ero nipinlẹ Eko, Musiliu Akinsanya ti gbogbo eeyan mọ si MC Oluọmọ ni wọn ti n ba a daro iku ojiji to mu ẹgbọn rẹ obinrin, Alaaja Kibitiu Aduni Adenuga Akinsanya, lọ.
ALAROYE gbọ pe ni nnkan bii ọwọ irọlẹ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kẹrindinlọgbọn, oṣu Kẹwaa yii, se ni obinrin naa degbere faye lẹyin aisan ranpẹ.
A gbọ pe ọga awọn onimọto yii bara jẹ gidigidi nitori iku obinrin naa.
Funra ẹ lo tufọ iku ẹgbọn rẹ to da bii iya fun un lẹyin ti iya wọn ti ku lọdun to kọja. Lori ikanni Instagraamu re lo gbe e si pe ‘Ọrọ aye yii ko too pọn o! Pẹlu ẹdun ọkan ati adanu nla ni mo fi kede iku aunti mi, to tun jẹ iya mi Alaaja Kibitiu Aduni Adenuga Akinsanya, to ṣe iyebiye si mi ju lọ. Iku rẹ ba mi lojiji, ko si ti i kuro lara mi di bi mo ṣe n sọ yii.
Lẹyin ti iya wa papoda, Alaaja lo duro bii iya fun wa, to si n ṣe ojuṣe rẹ fun itẹsiwaju ati alaafia ẹbi wa. Ko si ẹni to le rọpo rẹ, bẹẹ ni yoo ṣoro fun wa lati ri ẹni ti yoo di alafo ti iku rẹ fi silẹ.
Afi bii Mecca ni gbogbo awọn onimọto atawọn ololufẹ MC Oluọmọ n rọ lọ si ile ọkunrin naa lati lọọ ba a kẹdun iku to pa obinrin yii. Adura ni gbogbo wọn si n ṣe fun un pe Ọlọrun yoo wo awọn ọmọ to fi saye lọ, yoo si tu mọlẹbi Akinsanya funra ẹ ninu.