Faith Adebọla
Ilu-mọ-ọn-ka ajijagbara ilẹ Yoruba nni, Sunday Adeyẹmi, ti inagijẹ rẹ n jẹ Sunday Igboho ti ṣalaye pe irọ lawọn eeyan n pa mọ oun pe oun sọrọ si gbajugbaja ojiṣẹ Ọlọrun ati adari ijọ Ridiimu, Pasitọ Enoch Adejare Adeboye, o ni awọn alabosi ni wọn n sọsọkusọ kiri, ko sohun to jọ bẹẹ.
Ninu fidio kan ti Sunday Igboho ṣe ni Koiki Media lọjọ Aiku, Sannde yii, o ni oun ti gbọ gbogbo awuyewuye to n lọ nigboro lori ọro ọhun, o si ya oun lẹnu pe awọn kan le fẹẹ maa lo ọrọ toun sọ ṣaaju lati da ija silẹ.
O ni: “Ọta Yoruba lawọn to n sọrọkọrọ yii, wọn si n tan ara wọn ni. Wọn ni mo bu Baba Adeboye, irọ ni o, emi o bu baba yẹn o. Baba wa ni wọn, mi o jẹ bu wọn. Kristẹni ni mi. Ka ni mo jẹ Musulumi ni, wọn iba ni boya mo fẹẹ ki ọrọ ẹsin bọ ọ ni, ṣugbọn Kristẹni ni mi, kin ni mo fẹẹ maa bu Baba Adeboye fun.
“Ẹni ba lọọ wo fidio yẹn maa ri i pe alaye ọrọ ni mo ṣe pe ọrọ Yoruba Nation, ko si tọrọ ẹsin nibẹ, a o si fi ti ẹlẹyamẹya ṣe. Awọn oloṣelu, awọn agbalaga ati awọn alagbara ilẹ Yoruba to yẹ ki wọn dide lati ran wa lọwọ, ti wọn dẹ ri i bi iya ṣe n jẹ wa, ti agbara si wa lọwọ wọn, ṣugbọn ti wọn o ṣaanu ilẹ Yoruba ni mo n ba wi, mo si ṣepe gidi fun wọn, tori wọn o laaanu wa, ki i ṣe Baba Adeboye rara.
“Baba wa ni Baba Adeboye, loootọ mi o mọ wọn ri, awọn naa o si mọ mi ri, ohun to si ṣẹlẹ ni ti iku ọmọ wọn, eeyan ki i fi iku yọ ẹda laye, tori gbogbo wa la maa ku. Ṣe inu mi waa dun si ọmọ wọn to ku ni, abi to ba wa laye, ṣe oun naa ko ni i ni ipa to maa ko ni. Ko si sẹni ti o ni i ku. Emi o bu Baba Adeboye o, awọn alabosi ni wọn n sọsọkusọ o.
“K’Ọlọrun ṣaforiji fun gbogbo wa, ki Ọlọrun si tẹ oloogbe si afẹfẹ rere, ki Ọlọrun si tubọ lọra ẹmi Baba Adeboye. Baba Adeboye funra wọn ti wo fidio yẹn, wọn mọ pe mi o bu awọn. Emi mọ idi tawọn eeyan kan fi n gbe fidio yẹn lati fi sọ ọrọ buruku. K’Ọlọrun dariji awọn to n gbe ọrọ ti o ri bẹẹ kiri.”