Mi o fẹ irọ tawọn ọlọpaa n pa yii o, awọn Fulani ko maaluu wọ ile mi – Wọle Ṣoyinka

Gbajugbaja onkọtan ati ọmọwe ilẹ wa nni, Ọjọgbọn Wọle Ṣoyinka, ti fẹsun kan ileeṣẹ ọlọpaa pe ko sootọ ninu ọrọ ti wọn sọ nipa iṣẹlẹ awọn darandaran to ṣakọlu si ile rẹ lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, to kọja yii, o ni irọ lawọn ọlọpaa n pa, oun o si nifẹẹ siru irọ bẹẹ.

Ninu atẹjade kan ti Ṣoyinka funra rẹ buwọ lu l’Ọjọbọ, Tọsidee yii, o ṣalaye bi iṣẹlẹ naa ṣe waye gan-an. O ni ọrọ naa ki i ṣe pe ẹyọ maaluu kan tabi meji kan ṣirin wọ ọdọ oun, odidi agbo maaluu rẹpẹtẹ ni wọn ya bo ọgba ile toun n gbe.

 

Ṣoyinka ni, “Tori awọn ti wọn fẹẹ mọ ootọ bọrọ ṣe jẹ gan-an nipa iṣẹlẹ to waye ni Ijẹgba, mo n fidi ẹ mulẹ bayii pe ko sẹnikẹni to kọ lu emi funra mi o, nnkan kan o ṣe mi lagoọ ara, emi naa o si kọ lu maaluu kankan. Ṣugbọn awọn maaluu atawọn darandaran kọ lu ile mi, wọn kọlu ọgba mi, ki i si i ṣe igba akọkọ pẹlu.

“Bawo lawọn ọlọpaa ṣe maa pa iru irọ bẹẹ yẹn pe ko si maaluu to ṣakọlu si ile mi? Wọn ṣakọlu daadaa. Ọpẹlọpẹ awọn to n ba mi ṣiṣẹ ti wọn ti mọ nipa wọn, awọn ni wọn ṣakitiyan lati le wọn bọ sita. Ọlọrun si ṣe e, emi ti wa ninu mọto, mo n jade lọ tẹlẹ ni tiṣẹlẹ naa fi waye, niṣe ni mo n fi ọwọ kan wakọ, ti mo si n fi ọwọ kan le awọn maaluu, titi ti mo fi dọgbọn wa ara mi kuro laarin wọn.

“Igba ti mo de ita, mo bọọlẹ, mo si wawọ sawọn darandaran naa pe ki wọn sun mọ mi. Wọn kọkọ ṣe bii ẹni pe awọn o gbọ ohun ti mo wi, ṣugbọn nigba ti mo n rin lọ sọdọ wọn, wọn bẹ sinu igbo, wọn fi maaluu wọn silẹ, wọn sa lọ. La ba da maaluu wọn duro soju-kan nibẹ, mo si ran oṣiṣẹ mi kan, Taiwo, pe ko lọọ ba mi pe awọn ọlọpaa wa.

“Igba tawọn ọlọpaa o tete de, emi funra mi bọ si mọto, mo fẹẹ lọọ ba wọn, ṣugbọn niṣẹ ni mo pade ̄mọto wọn lọna, a si jọ debi iṣẹlẹ naa. Awọn ọlọpaa fẹẹ maa wa awọn darandaran to sa lọ naa ninu igbo, ṣugbọn mo ni ko niidi, niṣe ni ki wọn ko maaluu wọn pamọ, to ba ya, ẹni to ni maaluu aa yọju. Igba to si ya loootọ, onimaaluu naa yọju.

Inu mi o dun rara si ọrọ tawọn ọlọpaa n sọ yẹn pe maaluu ko wọle mi, ile ki i ṣe ogiri ati yara nikan, apakan ile mi ni gbogbo ọgba ati ayika mi kẹ! Awọn ọlọpaa tun parọ pe maaluu kan si meji lo kan ya bara, irọ niyẹn, gbogbo agbo ẹran ni, a ya fọto wọn, a tun fidio wọn pẹlu, ki ni wọn waa n parọ fun? Ko sidii to fi yẹ ki wọn ṣe yẹn, ko si ba iwa agbofinro gidi mu, koda ọrọ ti wọn sọ naa mu ifura dani, boya wọn ti gbabọde pẹlu. Tawọn ọlọpaa ba ni ki n mu ẹri wa, ẹ jẹ ki n sọ ọ kedere pe tawọn maaluu ba tun ya inu ọgba mi bẹẹ yẹn nigba mi-in, ma a ranṣẹ pe wọn pe ki wọn waa ba wa jẹ suya, igba yẹn ni wọn aa too mọ pe ṣereṣere kọ.”

Leave a Reply