Mi o jẹ Murphy Afọlabi lowo ko too ku, wọn parọ mọ mi ni – Adunni Ade

Monisọla Saka

Arẹwa oṣere tiata ilẹ wa, ṣugbọn ti wọn bi nilẹ Amẹrika, Adunni Adewale, tọpọ eeyan mọ si Adunni Ade, ti jade lati wẹ ara ẹ mọ ta ko ẹsun ti awọn kan fi n kan an pe o jẹ Oloogbe Murphy Afọlabi lowo ko too di pe ọkunrin naa ku.

Awuyewuye ọhun bẹrẹ lọjọ ti wọn n ṣe adura ọjọ kẹjọ fun Murphy Afọlabi, iyẹn lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kejilelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, nilana ẹsin Musulumi.

Lasiko ti wọn n ṣeto ikowojọ fawọn ọmọ ati ẹbi oloogbe to faye silẹ lẹyin ti wọn lo ṣubu ninu baluwẹ lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kẹrinla, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni awọn aafaa kede pe kawọn ti wọn ba jẹ oku lowo jade sita lati fara han, ki wọn si ri i daju pe awọn san an.

Nibẹ ni ọkan ninu awọn aafaa ti wọn pe ni Alfulany, ti pariwo orukọ Adunni laarin ero pe ko waa san gbese ẹgbẹrun lọna igba Naira ati aabọ (250,000) to ya lọwọ Murphy Afọlabi.

Bo tilẹ jẹ pe wọn ni obinrin yii atawọn onitiata mi-in ni wọn jẹ Murphy lowo, orukọ Adunni nikan ni aafaa ọhun pe laarin ero.

Adunni ko sọ nnkan kan ni gbogbo igba tọrọ naa n gbona lọwọ. Ṣugbọn lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, ni obinrin to da bii oyinbo yii gba ori Instagraamu rẹ lọ, pẹlu aworan iwe banki to ṣalaye bi owo ṣe n wọle, to n jade, ninu aṣunwọn banki rẹ lati tan imọlẹ si ọrọ naa.

O ni akokọ ni pe, ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira (150,000), ni owo to da oun ati Murphy pọ, oun si ti san an fun un ko too fi aye silẹ.

Adunni ni,  “Ninu oṣu Keje, ọdun 2021, Oloogbe Murphy Afọlabi pe mi pe ma a ba oun ṣiṣẹ ninu fiimu oun kan. O bẹ mi pe iṣẹ adaṣe to jẹ pe oun loun fẹẹ da owo idi ẹ na ni, nitori bẹẹ, oun ko ni le sanwo mi bo ṣe yẹ ki n gba a, ṣugbọn oun nilo iranlọwọ mi lori ẹ. Mo beere iye ọna ti ma a ti han ninu ere yẹn, o si da mi lohun pe ọna mẹwaa ni, ati pe ọjọ kan ṣoṣo naa ni mo maa lo loko ere.

“Lati tubọ mu nnkan rọrun, o loun maa ra epo si ọkọ mi lati fi ṣe koriya ati ẹmi imoore. Lọjọ keji, oṣu Keje, ọdun 2021 ọhun ni wọn san ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira sinu akanti mi. Amọ ka too bẹrẹ iṣẹ yẹn, ọfọ ṣẹ mi lọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọhun, mo padanu aburo mi.

‘‘Bii ọjọ meloo kan lẹyin rẹ naa ni mo pe Murphy pe mo maa ni lati da owo pada fun un, nitori mo n lọ si ọdọ awọn mọlẹbi mi l’Amẹrika, lati le ṣe ẹyẹ ikẹyin fun aburo mi to jade laye.

“Amọ Murphy taku pe ki n ṣi mu owo yẹn dani na, o loun yoo maa ro o, pe boya kawọn sun ọjọ tawọn yoo ya iṣẹ yẹn siwaju, tabi ki n fi ba oun ṣiṣẹ mi-in lọjọ iwaju.

‘‘Nigba to tun di ọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa, ọdun 2021, Murphy Afọlabi tun pe mi pe oun maa bẹrẹ iṣẹ mi-in laipẹ, ati pe oun maa nilo mi fun ọjọ mẹrin gbako, pe emi ni mo maa kopa to pọ ju lọ, bẹẹ ẹgbẹrun lọna aadọjọ Naira to ti san fun mi lati inu oṣu Keje yẹn naa lo fẹ ko jẹ owo iṣẹ mi. Pẹlu ọwọ ati apọnle ni mo fi kọ ọ, pe mi o le ṣe e, lojuẹsẹ naa ni mo ti beere fun nọmba akaunti banki rẹ, ti mo si da owo yẹn pada fun un lodiidi lọjọ kẹjọ, oṣu Kẹwaa, yẹn naa”.

Adunni waa pe akiyesi awọn eeyan si awọn aworan to gbe si abẹ ọrọ to kọ pe ki wọn wo ọjọ ati asiko ti Murphy sanwo foun, atigba toun da a pada fun un.

Awọn oṣere tiata bii Wunmi Toriọla, Alesh Sanni ati Nkechi Blessing ni wọn ti kọkọ n fi ẹdun kan wọn han lori ẹsun ti wọn fi kan oṣere ẹgbẹ wọn yii.

Wunmi ni, “Eyi ga o. Temi ni mo ro pe o pọ, ẹgbin ma jẹ Adunni o”.

Lati fi han an pe oun wa pẹlu ẹ, Nkechi Blessing ni, “Ti wọn ba ti koriira eeyan lagboole tiata wọn yẹn, gbogbo ọna ni wọn yoo wa, agaga awọn ti wọn wa nipo aṣẹ, lati ri i pe wọn ja iru ẹni bẹẹ bọ. A dupẹ pe Ọlọrun ko da bii eniyan. Ko buru o”.

Ọpọlọpọ awọn eeyan lori ẹrọ ayelujara ni wọn koro oju si ẹsin ti wọn fi arẹwa oṣere yii ṣe ati iru ẹgbin ti wọn fi lọ ọ. Bẹẹ ni wọn kan saara si i fun iru ọgbọn to lo lati fi yanju ọrọ naa, paapaa ju lọ bo ṣe n tọju bi owo ṣe n wọle, to n jade ninu banki rẹ, wọn ni nnkan to fi ri ara ẹ wẹ mọ ninu ọrọ ọhun niyẹn.

 

Leave a Reply