Mi o le ṣatilẹyin fun Tinubu lati depo aarẹ lae lae-Ṣẹgun Oni

 Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti

Gomina tẹlẹ nipinlẹ Ekiti, to tun jẹ oludije funpo naa lọdun to kọja labẹ ẹgbẹ oṣelu Social Democratic Party, Ṣẹgun Oni, ti ṣọ pe irọ pata to jinna soootọ ni aheso kan ti won n gbe kiri pe oun ati ojugba rẹ toun naa jẹ gomina ipinlẹ naa tẹlẹ, Ayọ Fayoṣe, n ṣa gbogbo ipa lati ṣatilẹyin fun oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu lati di aarẹ lasiko eto idibo ọsẹ to n bọ yii.

Adari eto ipolongo ibo Oni to gbẹnu rẹ sọrọ, Jackson Adebayọ, ṣalaye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹtadinlogun, oṣu Keji yii, pe ọrọ ti Ọgbẹni Oyetunde Ojo ati ẹgbẹ kan ti wọn n pe ni South West Agenda (SWAGA), sọ pe oun ati Fayoṣe n gbimọ pọ lati ṣiṣẹ pọ lati ṣatilẹyin fun Tinubu ko ri bẹẹ rara, o ni irọ buruku to jinna soootọ ni, ati pe ọkunrin naa ko mọ ohun to n sọ ni.

O ni, lae fabada, oun ko le ṣiṣẹ fun Tinubu. Ṣẹgun Oni ni oju ẹsẹ Tinubu han ketekete gẹgẹ bii ẹni to ṣatilẹyin fawọn to ṣeru ibo gomina Ekiti to kọja yii lati ṣegbe lẹyin ẹgbẹ APC. O ni wọn ko faaye gba awọn agbẹjọro oun lati ṣayẹwo ẹrọ ti wọn fi n wo iye awọn oludibo ‘Bimodal Voters Accreditation System’ (BVAS), gẹgẹ bi wọn ṣe ṣe nipilẹ Ọṣun, bo tilẹ jẹ pe ẹẹmeji ọtọọtọ ni igbimọ to n gbọ ẹjọ naa paṣẹ fun ajọ eleto idibo pe ki wọn gba awọn laaye lati ṣe bẹẹ.

Yato si eyi, Oni ni oun ko le gbagbe ipa to ko lori awọn idajọ arumọjẹ to gbe oun kuro nipo lọdun diẹ sẹyin.

O waa kilọ fawọn to n gbe ahesọ naa kiri pe ki wọn ma tan oun ni suuru o. O ni oun ko mọ ohun to le mu ki awọn eeyan naa maa ko oun pọ mọ Fayọṣe lati sọ pe awọn fẹẹ ṣiṣẹ fun Tinubu.

Leave a Reply