Monisọla Saka
Ishaku Elisha Abbo, Sẹnetọ to n ṣoju apa Ariwa Adamawa ti kọwe fipo silẹ gẹgẹ bii ọkan lara awọn to n polongo ibo fun Bọla Ahmed Tinubu ti ẹgbẹ APC fa kalẹ lati ṣoju wọn ninu ibo aarẹ to n bọ lọna.
Ko ti i ju bii wakati meloo kan lẹyin ti Tinubu mu gomina ipinlẹ Borno tẹlẹ, Kashim Shettima, gẹgẹ bii ẹni ti yoo ṣe igbakeji rẹ ninu idije ipo aarẹ ti Abbo fi yọwọ-yọsẹ ninu eto ipolongo ibo ẹ.
Nigba to n ṣalaye idi to fi gbe iru igbesẹ bẹẹ fawọn akọroyin lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkanla, oṣu Keje, ọdun 2022 yii, niluu Abuja, o ni Tinubu kọ eti ikun si abọ iwadii toun gbe siwaju rẹ lati ma ṣe mu Musulumi gẹgẹ bii igbakeji rẹ.
Gẹgẹ bo ṣe sọ, awọn ikọ ti wọn ni ki wọn wa igbakeji fun Tinubu fẹnu ko pe ki Aṣiwaju ma ṣe mu Musulumi, ati pe Tinubu kọ lati kọgbọn lati ara ọrọ Buhari to yan Kiristẹni gẹgẹ bii igbakeji rẹ lọdun 2015.
O ni, “Fun Tinubu lati gba tikẹẹti ko si yi i pada lati ṣe ohun ti ọwọ rẹ ko to lọdun 2015 pẹlu bi awọn ijọ Katoliiki atawọn olori ẹsin Kiristẹni mi-in ko ṣe ṣe tiẹ ko boju mu rara.
“Buhari jagun abẹlẹ, o si mọ atubọtan orilẹ-ede ti ko fimọ ṣọkan. Nigba ti Tinubu fẹẹ ba Buhari ṣejọba gẹgẹ bii igbakeji ẹ lọdun 2015, Buhari ko gba fun un nitori pe o mọ riri iṣọkan.
“Abuja nibi yii naa la jokoo si lati jiroro, a si fẹnu ọrọ jona lori pe ko ma mu Musulumi gẹgẹ bii igbakeji, ṣugbọn Tinubu ko aba naa danu ni.
“Ẹri ọkan mi o le jẹ ki n ṣe ipolongo ibo fun Tinubu. Ọmọ ẹgbẹ ajọ Kiristẹni nilẹ Naijiria (CAN), ni mi, mi o le sọ pe mi o mọ wọn mọ. Ọmọ ẹgbẹ APC ṣi ni mi, ṣugbọn ọrọ orilẹ-ede mi ni ma a fi siwaju ko to kan ọrọ oṣelu.
“A o le ṣiṣẹ fun iru eeyan bẹẹ yẹn. Koda to ba jẹ Kiristẹni meji naa ni, ma a ta ko o nitori pe iduroṣinṣin orilẹ-ede yii lo jẹ mi logun. Ki Kiristẹni meji naa fẹẹ dupo yoo jẹ aidaa fawọn Musulumi bakan naa”.
Abbo ni Naijiria pin si meji ọgbọọgba laarin awọn Musulumi atawọn Kiristẹni ni.
O waa fi kun un pe ijọbakijọba to ba fẹ ki Musulumi jẹ aarẹ ati igbakeji rẹ ko tẹle ohun to tọ, wọn ko si le roju rere awọn Kiristẹni.