Adewale Adeoye
Oludasilẹ ati oluṣọagutan agba ṣọọṣi kan ti wọn n pe ni, ‘Citadel Global Community Church’ PasitọTunde Bakare, ti sọ pe oun ko ni i pe aarẹ tuntun ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan sipo lorileede yii, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ni aarẹ oun lae.
Pasitọ Bakare to mu lẹnu bii abẹ naa sọrọ yii di mimọ lọjọ Abamẹta, Satidee, ọjọ kẹtadinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, niluu Eko, nibi eto pataki kan to waye lori ẹro ayelujara (Zoom), laarin oun atawọn kan ti wọn wa loke okun.
Bakare ni lara idi pataki toun ko ṣe ni i pe Tinubu ni aarẹ oun ni pe eru wa ninu eto idibo tawọn ajọ INEC ilẹ wa ṣe, nibi ti wọn ti kede pe Tinubu lo wọle gẹgẹ bii aarẹ orileede yii.
Ọkunrin oniwaasu naa ni ko sohun meji tinu oun ko ṣe dun si bi Tinubu ṣe wọle ju pe awọn alaṣẹ ajọ INEC ilẹ wa ni wọn ṣeru ti Tinubu fi raaye wọle gẹgẹ bii aare orileede yii ninu ibọ to waye lọjọ kẹẹẹdọgbọn, oṣu Keji, ọdun 2023 yii.
Nigba tawọn kan n beere lọwọ rẹ boya o le ba Tinubu ṣejọba rẹ, Bakare ni, ‘Ohun ti mo sọ fun Aarẹ Buhari naa ni ma a sọ fun Tinubu, mo sọ fun Buhari pe nigba mi-in, mo maa n pe e ni aarẹ mi, nigba mi-in, mo si tun maa n pe e ni aarẹ orileede Naijiria, eyi ko ni itumọ si mi rara. Ọjọruu, Wesidee, to kọja lọ yii ni mo ṣi lọọ ba Buhari nile onigilaasi (Glass House) to n gbẹ ninu Aso Rock, niluu Abuja, ti mo si ba a sọ eyi to jẹ ootọ ọrọ. Mo jẹ ki gbogbo awọn aṣiṣe to ṣe pata, ati bo ṣe kuna ninu ijọba rẹ lati nu omije awọn araalu nu, koda, mo sọ fun un pe ki i ṣohun to daa rara bo ti fẹẹ gbejọba fun ẹni ti ko kunju oṣuwọn bayii.’
Pasitọ Bakare ni o digba ti wọn ba to yanju gbogbo eru ati mago-mago to wa ninu ibo to sọ Tinubu di aarẹ ilẹ yii, oun ko ni i pe Tinubu ni aarẹ oun lae, ṣugbọn oun yoo maa pe e ni aarẹ orileede Naijiria nikan ni.
Bẹẹ o ba gbagbe, Pasitọ Bakare naa wa lara awọn oloṣelu ọmọ ẹgbẹ APC ti wọn ra fọọmu lati dije dupo aarẹ ilẹ yii ni miliọnu lọna ọgọrun-un Naira (N100M) lọdun 2022, ṣugbọn to jẹ pe ko ni ibo ẹyọ kan ṣoṣo lakooko ti ibo abẹle ọhun waye. Bo tilẹ jẹ pe Bakare tun bu ẹnu atẹ lu u pe ki i ṣojulowo rara, ati pe b’oun ko ṣe nibọ kankan yii dara ju tẹni to jẹ pe ọna eru lo gba di aarẹ orileede yii lọ