Mi o ni ki babalawo pa ọkọ mi, mo kan fẹẹ ko dari aasiki rẹ sọdọ mi lasan ni- Olubunmi

Ọlawale Ajao, Ibadan

Ọpọ ninu awọn ero to wa ni kootu ibilẹ Ọja’ba, to wa ni Mapo, n’Ibadan, ni wọn lanu silẹ ti wọn ko le pa a de nigba ti iyawo ile kan, Olubunmi Feyiṣẹtan, jẹwọ niwaju igbimọ awọn adajọ kootu naa pe loootọ loun mu orukọ ọkọ oun, Kọlawọle Feyiṣetan lọ sile oniṣegun lati fun un gbẹ, ki wọn le dari gbogbo aásìkí ara ẹ tan sọdọ oun.

Olubunmi ko deede maa kakọ bẹẹ laarin ọpọ eeyan, o sọrọ naa lati jẹwọ ẹsun ti ọkọ ẹ fi kan an nile-ẹjọ l’Ọjọbọ, Tọside, ni.

Nigba to n ṣapejuwe iyawo ẹ gẹgẹ bii òbìlẹ̀jẹ́ eeyan lorilẹ aye, olupẹjọ ṣalaye pe “Gbogbo igbesi aye mi ni mo fi sin iyawo mi. Koda, mo tun fi odidi ile mi silẹ fun un, sibẹsibẹ, gbogbo ohun ti mo n ṣe yii ko tẹ ẹ lọrun, o tun mu orukọ mi lọ sile oloogun lati da igbesi aye mi ru.

O waa rọ ile-ẹjọ lati fopin si igbeyawo ọdun mẹẹẹdogun (15) to da oun ati olujẹjọ pọ, ki wọn si yọnda itọju awọn ọmọ wọn fun oun nitori oun ko fẹ ko kọ awọn ọmọ oun loogun ika.

Olujẹjọ ko ja ọkọ ẹ niyan lori ẹsun to fi kan an, o ni loootọ loun ṣoogun sọkunrin naa, ṣugbọn iwọnba ni ki wọn da oun lẹbi mọ nitori ki i kuku ṣe pe oun fẹẹ pa a, oun kan fẹẹ gba aasiki ara ẹ lasan ni.

“Mi o mu orukọ ẹ lọ sile oniṣegun lati pa a, mo kan fẹẹ fún un gbẹ lasan ni, mo fẹẹ gba aasiki ara ẹ, ki awọn eeyan le ro pe ẹsẹ̀ iyawo to fẹ le mi ni ko daa”, bẹẹ lobinrin oniṣowo naa sọ niwaju gbogbo eeyan ni kootu.

Igbimọ awọn adajọ kootu naa, eyi to ko Alhaji Suleiman Apanpa ati Alhaji Rafiu Raji sinu pẹlu Oloye Ọdunade Ademọla ti i ṣe olori wọn, ko wulẹ laagun jina lori ọrọ wọn. Lẹsẹkẹsẹ ni wọn fopin si igbeyawo ọdun mẹẹẹdogun naa.

Wọn waa paṣẹ fun Kọlawọle lati maa san ẹgbẹrun mẹfa mẹfa naira loṣooṣu fun itọju awọn ọmọ wọn mejeeji ti wọn yọnda fun olujẹjọ.

Leave a Reply